LORI ibuṣọ́ mi li emi o duro, emi o si gbe ara mi kà ori alore, emi o si ṣọ lati ri ohun ti yio sọ fun mi, ati èsi ti emi o fọ́, nigbati a ba mba mi wi. Oluwa si da mi lohùn, o si wipe, Kọ iran na, ki o si hàn a lara wàlã, ki ẹniti nkà a, le ma sare. Nitori iran na jẹ ti igbà kan ti a yàn, yio ma yára si igbẹhìn, kì yio si ṣeke, bi o tilẹ̀ pẹ, duro dè e, nitori ni dide, yio de, kì yio pẹ. Kiyesi i, ọkàn rẹ̀ ti o gbega, kò duro ṣinṣin ninu rẹ̀: ṣugbọn olododo yio wà nipa ìgbagbọ́ rẹ̀.
Kà Hab 2
Feti si Hab 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Hab 2:1-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò