ỌLỌRUN si ranti Noa, ati ohun alãye gbogbo, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀: Ọlọrun si mu afẹfẹ kọja lori ilẹ, omi na si fà. A si dí gbogbo isun ibú ati awọn ferese ọrun, o si mu òjo dá lati ọrun wá. Omi si npada kuro lori ilẹ, lojojumọ lẹhin ãdọjọ ọjọ́, omi si fà. Ọkọ̀ si kanlẹ li oṣù keje, ni ijọ́ kẹtadilogun oṣù, lori oke Ararati. Omi si nfà titi o fi di oṣù kẹwa: li oṣù kẹwa, li ọjọ́ kini oṣù li ori awọn okenla hàn, O si ṣe li opin ogoji ọjọ́, ni Noa ṣí ferese ọkọ̀ ti o kàn: O si rán ìwo kan jade, ti o fò jade lọ ka kiri titi omi fi gbẹ kuro lori ilẹ. O si rán oriri kan jade, lati ọdọ rẹ̀ lọ, ki o wò bi omi ba nfà kuro lori ilẹ; Ṣugbọn oriri kò ri ibi isimi fun atẹlẹsẹ̀ rẹ̀, o si pada tọ ọ lọ ninu ọkọ̀, nitoriti omi wà lori ilẹ gbogbo: nigbana li o si nawọ rẹ̀, o mu u, o si fà a si ọdọ rẹ̀ ninu ọkọ̀. O si duro li ọjọ́ meje miran si i: o si tun rán oriri na jade lati inu ọkọ̀ lọ. Oriri na si pada wọle tọ̀ ọ wá li aṣalẹ; si kiyesi i, o já ewe olifi si ẹnu rẹ̀: bẹ̃li Noa si mọ̀ pe omi ngbẹ kuro lori ilẹ. O si tun duro ni ijọ́ meje miran, o si rán oriri na jade; ti kò si tun pada tọ̀ ọ wá mọ́.
Kà Gẹn 8
Feti si Gẹn 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 8:1-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò