NIGBANA ni Josefu kò le mu oju dá mọ́ niwaju gbogbo awọn ti o duro tì i; o si kigbe pe, Ẹ mu ki gbogbo enia ki o jade kuro lọdọ mi. Ẹnikẹni kò si duro tì i, nigbati Josefu sọ ara rẹ̀ di mimọ̀ fun awọn arakunrin rẹ̀. O si sọkun kikan: ati awọn ara Egipti ati awọn ara ile Farao gbọ́. Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi ni Josefu; baba mi wà sibẹ̀? awọn arakunrin rẹ̀ kò si le da a lohùn; nitori ti ẹ̀ru bà wọn niwaju rẹ̀. Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi bẹ̀ nyin ẹ sunmọ ọdọ mi. Nwọn si sunmọ ọ. O si wi pe, Emi ni Josefu, arakunrin nyin, ti ẹnyin tà si Egipti. Njẹ nisisiyi, ẹ máṣe binujẹ, ki ẹ má si ṣe binu si ara nyin, ti ẹnyin tà mi si ihin: nitori pe, Ọlọrun li o rán mi siwaju nyin lati gbà ẹmi là. Lati ọdún meji yi ni ìyan ti nmú ni ilẹ: o si tun kù ọdún marun si i, ninu eyiti a ki yio ni itulẹ tabi ikorè. Ọlọrun si rán mi siwaju nyin lati da irú-ọmọ si fun nyin lori ilẹ, ati lati fi ìgbala nla gbà ẹmi nyin là. Njẹ nisisiyi, ki iṣe ẹnyin li o rán mi si ihin, bikoṣe Ọlọrun: o si ti fi mi ṣe baba fun Farao, ati oluwa gbogbo ile rẹ̀, ati alakoso gbogbo ilẹ Egipti.
Kà Gẹn 45
Feti si Gẹn 45
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 45:1-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò