Gẹn 35:1-29

Gẹn 35:1-29 YBCV

ỌLỌRUN si wi fun Jakobu pe, Dide goke lọ si Beteli ki o si joko nibẹ̀, ki o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, fun Ọlọrun, ti o farahàn ọ, nigbati iwọ sá kuro niwaju Esau, arakunrin rẹ. Nigbana ni Jakobu wi fun awọn ara ile rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ti o wà li ọdọ rẹ̀ pe, Ẹ mú àjeji oriṣa ti o wà lọwọ nyin kuro, ki ẹnyin ki o si sọ ara nyin di mimọ́, ki ẹnyin ki o si pa aṣọ nyin dà: Ẹ si jẹ ki a dide, ki a si goke lọ si Beteli; nibẹ̀ li emi o si gbé tẹ́ pẹpẹ kan fun Ọlọrun ti o da mi li ohùn li ọjọ́ ipọnju mi, ẹniti o si wà pẹlu mi li àjo ti mo rè. Nwọn si fi gbogbo àjeji oriṣa ti o wà lọwọ wọn fun Jakobu, ati gbogbo oruka eti ti o wà li eti wọn: Jakobu si pa wọn mọ́ li abẹ igi oaku ti o wà leti Ṣekemu. Nwọn si rìn lọ: ẹ̀ru Ọlọrun si mbẹ lara ilu ti o yi wọn ká, nwọn kò si lepa awọn ọmọ Jakobu. Bẹ̃ni Jakobu si wá si Lusi, ti o wà ni ilẹ Kenaani, eyinì ni Beteli, on ati gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀. O si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni El-bet-el: nitori pe nibẹ̀ li Ọlọrun tọ̀ ọ wá, nigbati o sá kuro niwaju arakunrin rẹ̀. Ṣugbọn Debora olutọ́ Rebeka kú, a si sin i nisalẹ Beteli labẹ igi oaku kan: orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Alloni-bakutu. Ọlọrun si tún farahàn Jakobu, nigbati o ti Padan-aramu bọ̀, o si sure fun u. Ọlọrun si wi fun u pe, Jakobu li orukọ rẹ: a ki yio pè orukọ rẹ ni Jakobu mọ́, bikoṣe Israeli li orukọ rẹ yio ma jẹ́: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Israeli. Ọlọrun si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare: ma bisi i, si ma rẹ̀; orilẹ-ède, ati ẹgbẹ-ẹgbẹ orilẹ-ède ni yio ti ọdọ rẹ wá, awọn ọba yio si ti inu rẹ jade wá; Ati ilẹ ti mo ti fi fun Abrahamu ati Isaaki, iwọ li emi o fi fun, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ li emi o fi ilẹ na fun. Ọlọrun si lọ soke kuro lọdọ rẹ̀ ni ibi ti o gbé mbá a sọ̀rọ. Jakobu si fi ọwọ̀n kan lelẹ ni ibi ti o gbé bá a sọ̀rọ, ani ọwọ̀n okuta: o si ta ọrẹ ohun mimu si ori rẹ̀, o si ta oróro si ori rẹ̀. Jakobu si sọ orukọ ibi ti Ọlọrun gbé bá a sọ̀rọ ni Beteli. Nwọn si rìn lati Beteli lọ; o si kù diẹ ki nwọn ki o dé Efrati: ibi si tẹ̀ Rakeli: o si ṣoro jọjọ fun u. O si ṣe nigbati o wà ninu irọbí, ni iyãgba wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru: iwọ o si li ọmọkunrin yi pẹlu. O si ṣe, bi ọkàn rẹ̀ ti nlọ̀ (o sa kú) o sọ orukọ rẹ̀ ni Ben-oni: ṣugbọn baba rẹ̀ sọ ọ ni Benjamini. Rakeli si kú, a si sin i li ọ̀na Efrati, ti iṣe Betlehemu. Jakobu si fi ọwọ̀n kan lelẹ li oju-õri rẹ̀, eyinì ni Ọwọ̀n oju-õri Rakeli titi di oni-oloni. Israeli si nrìn lọ, o si pa agọ́ rẹ̀ niwaju ile iṣọ Ederi. O si ṣe nigbati Israeli joko ni ilẹ na, Reubeni si wọle tọ̀ Bilha, àle baba rẹ̀ lọ; Israeli si gbọ́. Njẹ awọn ọmọ Jakobu jẹ́ mejila. Awọn ọmọ Lea; Reubẹni, akọ́bi Jakobu, ati Simeoni, ati Lefi, ati Judah, ati Issakari, ati Sebuluni. Awọn ọmọ Rakeli; Josefu, ati Benjamini: Ati awọn ọmọ Bilha, iranṣẹbinrin Rakeli; Dani, ati Naftali: Ati awọn ọmọ Silpa, iranṣẹbinrin Lea; Gadi ati Aṣeri. Awọn wọnyi li ọmọ Jakobu, ti a bí fun u ni Padanaramu. Jakobu si dé ọdọ Isaaki baba rẹ̀, ni Mamre, si Kiriat-arba, ti iṣe Hebroni, nibiti Abrahamu ati Isaaki gbé ṣe atipo pẹlu. Ọjọ́ Isaaki si jẹ́ ọgọsan ọdún. Isaaki si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú, a si kó o jọ pẹlu awọn enia rẹ̀, o gbó, o si kún fun ọjọ́, awọn ọmọ rẹ̀, Esau ati Jakobu si sin i.