DINA ọmọbinrin Lea, ti o bí fun Jakobu si jade lọ lati wò awọn ọmọbinrin ilu na.
Nigbati Ṣekemu, ọmọ Hamori, ara Hiffi, ọmọ alade ilu na ri i, o mú u, o si wọle tọ̀ ọ, o si bà a jẹ́.
Ọkàn rẹ̀ si fà mọ́ Dina, ọmọbinrin Jakobu, o si fẹ́ omidan na, o si sọ̀rọ rere fun omidan na.
Ṣekemu si sọ fun Hamori baba rẹ̀ pe, Fẹ́ omidan yi fun mi li aya.
Jakobu si gbọ́ pe o ti bà Dina ọmọbinrin on jẹ́; njẹ awọn ọmọ rẹ̀ wà pẹlu awọn ẹran ni pápa: Jakobu si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ titi nwọn fi dé.
Hamori, baba Ṣekemu, si jade tọ̀ Jakobu lọ lati bá a sọ̀rọ.
Awọn ọmọ Jakobu si ti oko dé nigbati nwọn gbọ́: inu awọn ọkunrin na si bàjẹ́, inu si ru wọn gidigidi, nitori ti o ṣe ohun buburu ni Israeli, niti o bá ọmọbinrin Jakobu dàpọ: ohun ti a ki ba ti ṣe.
Hamori si bá wọn sọ̀rọ pe, Ọkàn Ṣekemu, ọmọ mi, nfẹ́ ọmọbinrin nyin; emi bẹ̀ nyin, ẹ fi i fun u li aya.
Ki ẹnyin ki o si bá wa gbeyawo, ki ẹnyin ki o si fi awọn ọmọbinrin nyin fun wa, ki ẹnyin ki o si ma mú awọn ọmọbinrin wa.
Ẹnyin o si ma bá wa gbé: ilẹ yio si wà niwaju nyin, ẹnyin o joko ki ẹ si ma ṣòwo ninu rẹ̀, ki ẹ si ma ní iní ninu rẹ̀.
Ṣekemu si wi fun baba omidan na ati fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki emi ri ore-ọfẹ li oju nyin, ohun ti ẹnyin o si kà fun mi li emi o fi fun nyin.
Ẹ bère ana lọwọ mi ati ẹ̀bun bi o ti wù ki o pọ̀ to, emi o si fi fun nyin gẹgẹ bi ẹnyin o ti kà fun mi: ṣugbọn ẹ fun mi li omidan na li aya.