Nigbana li ẹ̀ru bà Jakobu gidigidi, ãjo si mú u, o si pín awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, ati awọn ọwọ́-ẹran, awọn ọwọ́-malu, ati awọn ibakasiẹ, si ipa meji;
O si wipe, bi Esau ba kàn ẹgbẹ kan, ti o si kọlù u, njẹ ẹgbẹ keji ti o kù yio là.
Jakobu si wipe, Ọlọrun Abrahamu baba mi, ati Ọlọrun Isaaki baba mi, OLUWA ti o wi fun mi pe, pada lọ si ilẹ rẹ, ati sọdọ awọn ara rẹ, emi o si ṣe ọ ni rere:
Emi kò yẹ si kikini ninu gbogbo ãnu, ati ninu gbogbo otitọ, ti iwọ fihàn fun ọmọ-ọdọ rẹ, nitori pe, kìki ọpá mi ni mo fi kọja Jordani yi; nisisiyi emi si di ẹgbẹ meji.
Emi bẹ̀ ọ, gbà mi lọwọ arakunrin mi, lọwọ Esau: nitori ti mo bẹ̀ru rẹ̀, ki o má ba wá lati kọlù mi, ti iya ti ọmọ.
Iwọ si wipe, Nitõtọ emi o ṣe ọ ni rere, emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi iyanrin okun, ti a kò le kà fun ọ̀pọlọpọ.
O si sùn nibẹ̀ li alẹ ijọ́ na; o si mú ninu ohun ti o tẹ̀ ẹ li ọwọ li ọrẹ fun Esau, arakunrin rẹ̀;
Igba ewurẹ, on ogún obukọ, igba agutan, on ogún àgbo,
Ọgbọ̀n ibakasiẹ ti o ní wàra, pẹlu awọn ọmọ wọn, ogojì abo-malu on akọ-malu mẹwa, ogún abo-kẹtẹkẹtẹ, on ọmọ-kẹtẹkẹtẹ mẹwa.
O si fi wọn lé ọwọ́ awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ni ọ̀wọ́ kọkan; o si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Ẹnyin ṣaju mi, ki ẹ si fi àlàfo si agbedemeji ọwọ́-ọwọ.
O si fi aṣẹ fun eyiti o tète ṣaju wipe, Nigbati Esau, arakunrin mi, ba pade rẹ, ti o si bi ọ wipe, Ti tani iwọ? nibo ni iwọ si nrè? ati ti tani wọnyi niwaju rẹ?
Nigbana ni ki iwọ ki o wipe, Ti Jakobu iranṣẹ rẹ ni; ọrẹ ti o rán si Esau oluwa mi ni: si kiyesi i, on tikalarẹ̀ si mbẹ lẹhin wa.
Bẹ̃li o si fi aṣẹ fun ekeji, ati fun ẹkẹta, ati fun gbogbo awọn ti o tẹle ọwọ́ wọnni wipe, Bayibayi ni ki ẹnyin ki o wi fun Esau nigbati ẹnyin ba ri i.
Ki ẹnyin ki o wi pẹlu pe, Kiyesi i, Jakobu iranṣẹ rẹ mbọ̀ lẹhin wa. Nitori ti o wipe, Emi o fi ọrẹ ti o ṣaju mi tù u loju, lẹhin eyini emi o ri oju rẹ̀, bọya yio tẹwọgbà mi.
Bẹ̃li ọrẹ na si kọja lọ niwaju rẹ̀: on tikalarẹ̀ si sùn li oru na ninu awọn ẹgbẹ.