Gẹn 31:43-55

Gẹn 31:43-55 YBCV

Labani si dahùn o si wi fun Jakobu pe, Awọn ọmọbinrin wọnyi, awọn ọmọbinrin mi ni, ati awọn ọmọ wọnyi, awọn ọmọ mi ni, ati awọn ọwọ́-ẹran wọnyi ọwọ́-ẹran mi ni, ati ohun gbogbo ti o ri ti emi ni: kili emi iba si ṣe si awọn ọmọbinrin mi wọnyi loni, tabi si awọn ọmọ wọn ti nwọn bí? Njẹ nisisiyi, wá, jẹ ki a bá ara wa dá majẹmu, temi tirẹ; ki o si ṣe ẹrí lãrin temi tirẹ. Jakobu si mú okuta kan, o si gbé e ró ṣe ọwọ̀n. Jakobu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ ma kó okuta jọ; nwọn si kó okuta jọ, nwọn si ṣe òkiti: nwọn si jẹun nibẹ̀ lori òkiti na. Labani si sọ orukọ rẹ̀ ni Jegari-Sahaduta: ṣugbọn Jakobu sọ ọ ni Galeedi. Labani si wipe, Òkiti yi li ẹri lãrin temi tirẹ loni. Nitori na li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Galeedi: Ati Mispa; nitori ti o wipe, Ki OLUWA ki o ma ṣọ́ temi tirẹ nigbati a o yà kuro lọdọ ara wa. Bi iwọ ba pọ́n awọn ọmọbinrin mi li oju, tabi bi iwọ ba fẹ́ aya miran pẹlu awọn ọmọbinrin mi, kò sí ẹnikan pẹlu wa; wò o, Ọlọrun li ẹlẹri lãrin temi tirẹ. Labani si wi fun Jakobu pe, Wò òkiti yi, si wò ọwọ̀n yi, ti mo gbé ró lãrin temi tirẹ. Òkiti yi li ẹri, ọwọ̀n yi li ẹri, pe emi ki yio rekọja òkiti yi sọdọ rẹ; ati pe iwọ ki yio si rekọja òkiti yi ati ọwọ̀n yi sọdọ mi fun ibi. Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Nahori, Ọlọrun baba wọn, ni ki o ṣe idajọ lãrin wa. Jakobu si fi ẹ̀ru Isaaki baba rẹ̀ bura. Nigbana ni Jakobu rubọ lori oke na, o si pè awọn arakunrin rẹ̀ wá ijẹun: nwọn si jẹun, nwọn si fi gbogbo oru ijọ́ na sùn lori oke na. Ni kutukutu owurọ̀ Labani si dide, o si fi ẹnu kò awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ li ẹnu, o si sure fun wọn: Labani si dide, o si pada lọ si ipò rẹ̀.