Gẹn 3:7-10

Gẹn 3:7-10 YBCV

Oju awọn mejeji si là, nwọn si mọ̀ pe nwọn wà ni ìhoho; nwọn si gán ewe ọpọtọ pọ̀, nwọn si dá ibantẹ fun ara wọn. Nwọn si gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun, o nrìn ninu ọgbà ni itura ọjọ́: Adamu ati aya rẹ̀ si fi ara wọn pamọ́ kuro niwaju OLUWA Ọlọrun lãrin igi ọgbà. OLUWA Ọlọrun si kọ si Adamu, o si wi fun u pe, Nibo ni iwọ wà? O si wipe, Mo gbọ́ ohùn rẹ ninu ọgbà, ẹ̀ru si bà mi, nitori ti mo wà ni ìhoho; mo si fi ara pamọ́.