Gẹn 27:30-46

Gẹn 27:30-46 YBCV

O si ṣe, bi Isaaki ti pari ire isú fun Jakobu, ti Jakobu si fẹrẹ má jade tan kuro niwaju Isaaki baba rẹ̀, ni Esau, arakunrin rẹ̀ wọle de lati igbẹ́ ọdẹ rẹ̀ wá. On pẹlu si ti sè ẹran adidùn, o si mu u tọ̀ baba rẹ̀ wá, o si wi fun baba rẹ̀ pe, Ki baba mi ki o dide ki o si jẹ ninu ẹran-igbẹ́ ọmọ rẹ̀, ki ọkàn rẹ le sure fun mi. Isaaki baba rẹ̀ si bi i pe, Iwọ tani nì? on si wipe, Emi Esau, ọmọ rẹ akọbi ni. Isaaki si warìri gidigidi rekọja, o si wipe, Tani nla? tali ẹniti o ti pa ẹran-igbẹ́, ti o si gbé e tọ̀ mi wá, emi si ti jẹ ninu gbogbo rẹ̀, ki iwọ ki o to de, emi si ti sure fun u? nitõtọ a o si bukún fun u. Nigbati Esau gbọ́ ọ̀rọ baba rẹ̀, o fi igbe nlanla ta, o si sun ẹkun kikorò gidigidi, o si wi fun baba rẹ̀ pe, Sure fun mi, ani fun emi pẹlu, baba mi. O si wipe, Arakunrin rẹ fi erú wá, o si ti gbà ibukún rẹ lọ. O si wipe, A kò ha pè orukọ rẹ̀ ni Jakobu ndan? nitori o jì mi li ẹsẹ̀ ni ìgba meji yi: o gbà ogún-ibi lọwọ mi; si kiyesi i, nisisiyi o si gbà ire mi lọ. O si wipe, Iwọ kò ha pa ire kan mọ́ fun mi? Isaaki si dahùn o si wi fun Esau pe, Wõ, emi ti fi on ṣe oluwa rẹ, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ li emi ti fi ṣe iranṣẹ rẹ̀; ati ọkà ati ọti-waini ni mo fi gbè e: ewo li emi o ha ṣe fun ọ nisisiyi, ọmọ mi? Esau si wi fun baba rẹ̀ pe, Ire kanṣoṣo li o ni iwọ baba mi? sure fun mi, ani fun mi pẹlu, baba mi? Esau si gbé ohùn rẹ̀ soke, o sọkun. Isaaki baba rẹ̀ si dahùn o si wi fun u pe, Wõ, ibujoko rẹ yio jẹ ọrá ilẹ, ati ibi ìri ọrun lati oke wá; Nipa idà rẹ ni iwọ o ma gbé, iwọ o si ma sìn arakunrin rẹ; yio si ṣe nigbati iwọ ba di alagbara tan, iwọ o já àjaga rẹ̀ kuro li ọrùn rẹ. Esau si korira Jakobu nitori ire ti baba rẹ̀ su fun u: Esau si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọjọ́ ọ̀fọ baba mi sunmọ-etile; nigbana li emi o pa Jakobu, arakunrin mi. A si sọ ọ̀rọ Esau akọ́bi rẹ̀ wọnyi fun Rebeka: on si ranṣẹ o si pè Jakobu, ọmọ rẹ̀ aburo, o si wi fun u pe, Kiyesi i, Esau, arakunrin rẹ, ntù ara rẹ ninu niti rẹ lati pa ọ. Njẹ nisisiyi ọmọ mi, gbọ́ ohùn mi; si dide, sá tọ̀ Labani arakunrin mi lọ si Harani; Ki o si bá a joko ni ijọ́ melo kan, titi ibinu arakunrin rẹ yio fi tuka; Titi inu arakunrin rẹ yio fi tutu si ọ, ti yio si fi gbagbe ohun ti o fi ṣe e: nigbana li emi o ranṣẹ mu ọ lati ibẹ̀ wá: ẽṣe ti emi o fi fẹ́ ẹnyin mejeji kù ni ijọ́ kanṣoṣo? Rebeka si wi fun Isaaki pe, Agara aiye mi ma dá mi nitori awọn ọmọbinrin Heti, bi Jakobu ba fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Heti, bi irú awọn wọnyi yi iṣe ninu awọn ọmọbinrin ilẹ yi, aiye mi o ha ti ri?