ÌYAN kan si mu ni ilẹ na, lẹhin ìyan ti o tetekọ mu li ọjọ́ Abrahamu. Isaaki si tọ̀ Abimeleki, ọba awọn ara Filistia lọ, si Gerari.
OLUWA si farahàn a, o si wipe, Máṣe sọkalẹ lọ si Egipti; joko ni ilẹ ti emi o wi fun ọ.
Mã ṣe atipo ni ilẹ yi, emi o si pẹlu rẹ, emi o si bukún u fun ọ; nitori iwọ ati irú-ọmọ rẹ, li emi o fi gbogbo ilẹ wọnyi fun, emi o si mu ara ti mo bú fun Abrahamu, baba rẹ, ṣẹ.
Emi o si mu irú-ọmọ rẹ bisi i bi irawọ oju-ọrun, emi o si fi gbogbo ilẹ wọnyi fun irú-ọmọ rẹ; ati nipasẹ irú-ọmọ rẹ li a o bukún gbogbo orilẹ-ède aiye;
Nitoriti Abrahamu gbà ohùn mi gbọ́, o si pa ìlọ mi, aṣẹ mi, ìlana mi, ati ofin mi mọ́.
Isaaki si joko ni Gerari.
Awọn ọkunrin ibẹ̀ na bi i lẽre niti aya rẹ̀: o si wipe, Arabinrin mi ni: nitoriti o bẹ̀ru ati wipe, Aya mi ni; o ni, ki awọn ọkunrin ibẹ̀ na ki o má ba pa mi nitori Rebeka; nitoriti on li ẹwà lati wò.
O si ṣe nigbati o joko nibẹ̀ pẹ titi, ni Abimeleki, ọba awọn ara Filistia, wò ode li ojuferese, o si ri, si kiyesi i, Isaaki mba Rebeka aya rẹ̀ wẹ́.
Abimeleki si pè Isaaki, o si wipe, Kiyesi i, nitõtọ aya rẹ ni iṣe: iwọ ha ti ṣe wipe, Arabinrin mi ni? Isaaki si wi fun u pe, Nitoriti mo wipe, ki emi ki o má ba kú nitori rẹ̀.
Abimeleki si wipe, Kili eyiti iwọ ṣe si wa yi? Bí ọkan ninu awọn enia bá lọ bá aya rẹ ṣe iṣekuṣe nkọ? iwọ iba si mu ẹ̀ṣẹ wá si ori wa.
Abimeleki si kìlọ fun gbogbo awọn enia rẹ̀ wipe, Ẹnikẹni ti o ba tọ́ ọkunrin yi tabi aya rẹ̀, kikú ni yio kú.
Nigbana ni Isaaki funrugbìn ni ilẹ na, o si ri ọrọrún mu li ọdún na; OLUWA si busi i fun u:
Ọkunrin na si di pupọ̀, o si nlọ si iwaju, o si npọ̀ si i titi o fi di enia nla gidigidi.
Nitori ti o ni agbo-agutan, ati ini agbo-ẹran nla ati ọ̀pọlọpọ ọmọ-ọdọ: awọn ara Filistia si ṣe ilara rẹ̀.
Nitori gbogbo kanga ti awọn ọmọ-ọdọ baba rẹ̀ ti wà li ọjọ́ Abrahamu, baba rẹ̀, awọn ara Filistia dí wọn, nwọn si fi erupẹ dí wọn.
Abimeleki si wi fun Isaaki pe, Lọ kuro lọdọ wa; nitori ti iwọ lagbara pupọ̀ ju wa lọ.