Gẹn 24:1-27

Gẹn 24:1-27 YBCV

ABRAHAMU si gbó, o si pọ̀ li ọjọ́: OLUWA si ti busi i fun Abrahamu li ohun gbogbo. Abrahamu si wi fun iranṣẹ rẹ̀, agba ile rẹ̀ ti o ṣe olori ohun gbogbo ti o ni pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ọwọ rẹ si abẹ itan mi; Emi o si mu ọ fi OLUWA bura, Ọlọrun ọrun, ati Ọlọrun aiye, pe iwọ ki yio fẹ́ aya fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani, lãrin awọn ẹniti mo ngbé: Ṣugbọn iwọ o lọ si ilẹ mi, ati si ọdọ awọn ará mi, ki iwọ ki o si fẹ́ aya fun Isaaki, ọmọ mi. Iranṣẹ na si wi fun u pe, Bọya obinrin na ki yio fẹ́ ba mi wá si ilẹ yi: mo ha le mu ọmọ rẹ pada lọ si ilẹ ti iwọ gbé ti wá? Abrahamu si wi fun u pe, Kiyesara ki iwọ ki o má tun mu ọmọ mi pada lọ sibẹ̀. OLUWA Ọlọrun ọrun, ti o mu mi lati ile baba mi wá, ati lati ilẹ ti a bi mi, ẹniti o sọ fun mi, ti o si bura fun mi, wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun; on ni yio rán angeli rẹ̀ ṣaju rẹ, iwọ o si fẹ́ aya lati ibẹ̀ fun ọmọ mi wá. Bi obinrin na kò ba si fẹ́ tẹle ọ, njẹ nigbana li ọrùn rẹ yio mọ́ kuro ni ibura mi yi: ọkan ni, ki iwọ máṣe tun mu ọmọ mi pada lọ sibẹ̀. Iranṣẹ na si fi ọwọ́ rẹ̀ si abẹ itan Abrahamu oluwa rẹ̀, o si bura fun u nitori ọ̀ran yi. Iranṣẹ na si mu ibakasiẹ mẹwa, ninu ibakasiẹ oluwa rẹ̀, o si lọ; nitori pe li ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ẹrù oluwa rẹ̀ wà: o si dide, o si lọ si Mesopotamia, si ilu Nahori. O si mu awọn ibakasiẹ rẹ̀ kunlẹ lẹhin ode ilu na li ẹba kanga omi kan nigba aṣalẹ, li akokò igbati awọn obinrin ima jade lọ pọnmi. O si wipe, OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, ṣe ọ̀na mi ni rere loni, ki o si ṣe ore fun Abrahamu oluwa mi. Kiyesi i, emi duro li ẹba kanga omi yi; awọn ọmọbinrin ara ilu na njade wá lati pọnmi: Ki o si jẹ ki o ṣe pe, omidan ti emi o wi fun pe, Emi bẹ̀ ọ, sọ ladugbo rẹ kalẹ, ki emi ki o mu; ti on o si wipe, Mu, emi o si fi fun awọn ibakasiẹ rẹ mu pẹlu: on na ni ki o jẹ ẹniti iwọ yàn fun Isaaki iranṣẹ rẹ; nipa eyi li emi o si mọ̀ pe, iwọ ti ṣe ore fun oluwa mi. O si ṣe, ki on to pari ọ̀rọ isọ, kiyesi i, Rebeka jade de, ẹniti a bí fun Betueli, ọmọ Milka, aya Nahori, arakunrin Abrahamu, ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀. Omidan na li ẹwà gidigidi lati wò, wundia ni, bẹ̃li ẹnikẹni kò ti imọ̀ ọ: o si sọkalẹ lọ sinu kanga, o si pọn ladugbo rẹ̀ kún, o si goke. Iranṣẹ na si sure lọ ipade rẹ̀, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki nmu omi diẹ ninu ladugbo rẹ. O si dahùn pe, Mu, oluwa mi: o si yara, o sọ̀ ladugbo rẹ̀ ka ọwọ́, o si fun u mu. Nigbati o si fun u mu tan, o si wipe, Emi o pọn fun awọn ibakasiẹ rẹ pẹlu, titi nwọn o fi mu tan. O si yara, o si tú ladugbo rẹ̀ sinu ibumu, o si tun pada sure lọ si kanga lati pọn omi, o si pọn fun gbogbo awọn ibakasiẹ rẹ̀. Ọkunrin na si tẹjumọ ọ, o dakẹ, lati mọ̀ bi OLUWA mu ìrin on dara, bi bẹ̃kọ. O si ṣe, bi awọn ibakasiẹ ti mu omi tan, ni ọkunrin na mu oruka wurà àbọ ìwọn ṣekeli, ati jufù meji fun ọwọ́ rẹ̀, ti ìwọn ṣekeli wurà mẹwa; O si bi i pe, Ọmọbinrin tani iwọ iṣe? Emi bẹ̀ ọ, wi fun mi: àye wà ni ile baba rẹ fun wa lati wọ̀ si? On si wi fun u pe, Ọmọbinrin Betueli, ọmọ Milka, ti o bí fun Nahori, li emi iṣe. O si wi fun u pe, Awa ni koriko ati sakasáka tó pẹlu, ati àye lati wọ̀ si. Ọkunrin na si tẹriba, o si sìn OLUWA. O si wipe, Olubukún li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, ti kò jẹ ki ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ ki o yẹ̀ kuro lọdọ, oluwa mi, niti emi, OLUWA fi ẹsẹ̀ mi le ọ̀na ile awọn arakunrin baba mi.