Gẹn 2:1-4

Gẹn 2:1-4 YBCV

BẸ li a pari ọrun on aiye, ati gbogbo ogun wọn. Ni ijọ́ keje Ọlọrun si pari iṣẹ rẹ̀ ti o ti nṣe; o si simi ni ijọ́ keje kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti nṣe. Ọlọrun si busi ijọ́ keje, o si yà a si mimọ́; nitori pe, ninu rẹ̀ li o simi kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti bẹ̀rẹ si iṣe. Itan ọrun on aiye ni wọnyi nigbati a dá wọn, li ọjọ́ ti OLUWA Ọlọrun dá aiye on ọrun.