Gẹn 17:17-19

Gẹn 17:17-19 YBCV

Nigbana li Abrahamu dojubolẹ, o si rẹrin, o si wi li ọkàn rẹ̀ pe, A o ha bímọ fun ẹni ọgọrun ọdún? Sara ti iṣe ẹni ãdọrun ọdún yio ha bímọ bi? Abrahamu si wi fun Ọlọrun pe, Ki Iṣmaeli ki o wà lãye niwaju rẹ! Ọlọrun si wipe, Sara, aya rẹ, yio bí ọmọkunrin kan fun ọ nitõtọ; iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Isaaki: emi o fi idi majẹmu mi mulẹ pẹlu rẹ̀, ni majẹmu aiyeraiye, ati pẹlu irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀.