Gal 4:6-8

Gal 4:6-8 YBCV

Ati nitoriti ẹnyin nṣe ọmọ, Ọlọrun si ti rán Ẹmí Ọmọ rẹ̀ wá sinu ọkàn nyin, ti nke pe, Abba, Baba. Nitorina iwọ kì iṣe ẹrú mọ́, bikoṣe ọmọ; ati bi iwọ ba iṣe ọmọ, njẹ iwọ di arole Ọlọrun nipasẹ Kristi. Ṣugbọn nigbati ẹnyin kò ti mọ̀ Ọlọrun rí, ẹnyin ti nsìnrú fun awọn ti kì iṣe ọlọrun nipa ẹda.