Esr 8

8
Àwọn tí Wọ́n Pada láti Oko Ẹrú
1WỌNYI ni awọn olori ninu awọn baba wọn, eyi ti a kọ sinu iwe itan-idile awọn ti o ba mi goke lati Babiloni wá, ni ijọba Artasasta ọba.
2Ninu awọn ọmọ Finehasi, Gerṣomu: ninu awọn ọmọ Itamari, Danieli: ninu awọn ọmọ Dafidi, Hattuṣi.
3Ninu awọn ọmọ Ṣekaniah, ti awọn ọmọ Paroṣi, Ṣekariah: ati pẹlu rẹ̀ li a ka ãdọjọ ọkunrin nipa iwe itan-idile.
4Ninu awọn ọmọ Pahat-moabu; Elihoenai ọmọ Serahiah, ati pẹlu rẹ̀, igba ọkunrin.
5Ninu awọn ọmọ Ṣekaniah; ọmọ Jahasieli, ati pẹlu rẹ̀, ọdunrun ọkunrin.
6Ninu awọn ọmọ Adini pẹlu, Ebedi ọmọ Jonatani, ati pẹlu rẹ̀, ãdọta ọkunrin.
7Ati ninu awọn ọmọ Elamu; Jeṣaiah ọmọ Ataliah, ati pẹlu rẹ̀, ãdọrin ọkunrin.
8Ati ninu awọn ọmọ Ṣefatiah; Sebadiah ọmọ Mikaeli, ati pẹlu rẹ̀, ọgọrin ọkunrin.
9Ninu awọn ọmọ Joabu; Obadiah ọmọ Jahieli ati pẹlu rẹ̀, ogunlugba ọkunrin o din meji.
10Ati ninu awọn ọmọ Ṣelomiti; ọmọ Josafiah, ati pẹlu rẹ̀, ọgọjọ ọkunrin.
11Ati ninu awọn ọmọ Bebai; Sekariah, ọmọ Bebai, ati pẹlu rẹ̀, ọkunrin mejidilọgbọn.
12Ati ninu awọn ọmọ Asgadi; Johanani ọmọ Hakkatani, ati pẹlu rẹ̀, ãdọfa ọkunrin.
13Ati ninu awọn ọmọ ikẹhin Adonikamu, orukọ awọn ẹniti iṣe wọnyi, Elifeleti, Jeieli, ati Ṣemaiah, ati pẹlu wọn, ọgọta ọkunrin.
14Ninu awọn ọmọ Bigfai pẹlu; Uttai, ati Sabbudi, ati pẹlu wọn, ãdọrin ọkunrin.
15Mo si kó wọn jọ pọ li eti odò ti o ṣàn si Ahafa; nibẹ li a si gbe inu agọ li ọjọ mẹta: mo si wò awọn enia rere pẹlu awọn alufa, emi kò si ri ẹnikan ninu awọn ọmọ Lefi nibẹ.
16Nigbana ni mo ranṣẹ pè Elieseri, Arieli, Ṣemaiah, ati Elnatani ati Jaribi, ati Elnatani, ati Natani, ati Sekariah, ati Meṣullamu, awọn olori pẹlu Joiaribi, ati Elnatani, enia oloye.
17Mo si rán wọn ti awọn ti aṣẹ si ọdọ Iddo, olori ni ibi Kasifia, mo si kọ́ wọn li ohun ti nwọn o wi fun Iddo, ati fun awọn arakunrin rẹ̀, awọn Netinimu ni ibi Kasifia, ki nwọn ki o mu awọn iranṣẹ wá si ọdọ wa fun ile Ọlọrun wa.
18Ati nipa ọwọ rere Ọlọrun wa lara wa, nwọn mu ọkunrin oloye kan fun wa wá, ninu awọn ọmọ Mali, ọmọ Lefi, ọmọ Israeli; ati Ṣerebiah, pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, mejidilogun.
19Ati Haṣabiah, ati pẹlu rẹ̀ Jeṣaiah, ninu awọn ọmọ Merari, awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ wọn, ogún;
20Ninu awọn Netinimu pẹlu, ti Dafidi ati awọn ijoye ti fi fun isin awọn ọmọ Lefi, ogunlugba Netinimu gbogbo wọn li a kọ orukọ wọn.
21Nigbana ni mo kede àwẹ kan nibẹ lẹba odò Ahafa, ki awa ki o le pọn ara wa loju niwaju Ọlọrun wa, lati ṣafẹri ọ̀na titọ́ fun wa li ọwọ rẹ̀, ati fun ọmọ wẹrẹ wa, ati fun gbogbo ini wa.
22Nitoripe, oju tì mi lati bère ẹgbẹ ọmọ-ogun li ọwọ ọba, ati ẹlẹṣin, lati ṣọ wa nitori awọn ọta li ọ̀na: awa sa ti sọ fun ọba pe, Ọwọ Ọlọrun wa mbẹ lara awọn ti nṣe afẹri rẹ̀ fun rere; ṣugbọn agbara rẹ̀ ati ibinu rẹ̀ mbẹ lara gbogbo awọn ti o kọ̀ ọ silẹ.
23Bẹ̃li awa gbàwẹ, ti awa si bẹ̀ Ọlọrun wa nitori eyi: on si gbọ́ ẹ̀bẹ wa.
24Nigbana ni mo yàn ẹni-mejila si ọ̀tọ ninu awọn olori awọn alufa, Ṣerebiah, Haṣabiah, ati mẹwa ninu awọn arakunrin wọn pẹlu wọn,
25Mo si wọ̀n fàdaka ati wura fun wọn, ati ohun èlo, ani ọrẹ ti iṣe ti ile Ọlọrun wa, ti ọba ati awọn ìgbimọ rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo Israeli ti o wà nibẹ, ta li ọrẹ:
26Mo si wọ̀n ãdọtalelẹgbẹta talenti fàdaka le wọn li ọwọ, ati ohun èlo fàdaka, ọgọrun talenti, ati ti wura, ọgọrun talenti,
27Pẹlu ogun ago wura ẹlẹgbẹgbẹrun dramu, ati ohun èlo meji ti bàba daradara, ti o niye lori bi wura.
28Mo si wi fun wọn pe, Mimọ́ li ẹnyin si Oluwa; mimọ́ si li ohun èlo wọnyi; ọrẹ atinuwa si Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin ni fàdaka ati wura na.
29Ẹ ma tọju wọn, ki ẹ si ma pa wọn mọ, titi ẹnyin o fi wọ̀n wọn niwaju awọn olori ninu awọn alufa ati ọmọ Lefi, pẹlu awọn olori ninu awọn baba Israeli ni Jerusalemu, ninu iyàrá ile Oluwa.
30Bẹ̃ni awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi mu fàdaka ati wura ti a wọ̀n pẹlu ohun-èlo wọnni lati ko wọn wá si Jerusalemu, sinu ile Ọlọrun wa.
Pípadà sí Jerusalẹmu
31Nigbana ni awa lọ kuro ni odò Ahafa, li ọjọ ekejila oṣu ikini, lati lọ si Jerusalemu: ọwọ Ọlọrun wa si wà lara wa, o si gba wa lọwọ awọn ọta, ati lọwọ iru awọn ti o ba ni ibuba li ọ̀na.
32Awa si de Jerusalemu, awa si simi nibẹ li ọjọ mẹta.
33Li ọjọ ẹkẹrin li a wọ̀n fàdaka ati wura ati ohun-èlo wọnni ninu ile Ọlọrun wa si ọwọ Meremoti ọmọ Uriah, alufa, ati pẹlu rẹ̀ ni Eleasari ọmọ Finehasi; ati pẹlu wọn ni Josabadi ọmọ Jeṣua, ati Noadia, ọmọ Binnui, awọn ọmọ Lefi;
34Nipa iye, ati nipa ìwọn ni gbogbo wọn: a si kọ gbogbo ìwọn na sinu iwe ni igbana.
35Ọmọ awọn ti a ti ko lọ, awọn ti o ti inu igbekùn pada bọ̀, ru ẹbọ sisun si Ọlọrun Israeli, ẹgbọrọ malu mejila, àgbo mẹrindilọgọrun, ọdọ-agutan mẹtadilọgọrin, ati obukọ mejila fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: gbogbo eyi jẹ ẹbọ sisun si Oluwa.
36Nwọn si fi aṣẹ ọba fun awọn ijoye ọba, ati fun awọn balẹ ni ihahin odò: nwọn si ràn awọn enia na lọwọ, ati ile Ọlọrun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Esr 8: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀