Esr 10:18-44

Esr 10:18-44 YBCV

Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa, a ri awọn ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe: ninu awọn ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati awọn arakunrin rẹ̀; Maaseiah, ati Elieseri, ati Jaribi ati Gedaliah. Nwọn si fi ọwọ wọn fun mi pe: awọn o kọ̀ awọn obinrin wọn silẹ; nwọn si fi àgbo kan rubọ ẹ̀ṣẹ nitori ẹbi wọn. Ati ninu awọn ọmọ Immeri; Hanani ati Sebadiah. Ati ninu awọn ọmọ Harimu; Maaseiah, ati Elija, ati Ṣemaiah, ati Jehieli, ati Ussiah. Ati ninu awọn ọmọ Paṣuri; Elioenai, Maaseiah, Iṣmaeli, Nataneeli Josabadi, ati Eleasa. Ati ninu awọn ọmọ Lefi; Josabadi, ati Ṣimei, ati Kelaiah (eyi ni Kelita) Petahiah, Juda, ati Elieseri. Ninu awọn akọrin pẹlu; Eliaṣibu: ati ninu awọn adèna; Ṣallumu, ati Telemi, ati Uri. Pẹlupẹlu ninu Israeli: ninu awọn ọmọ Paroṣi: Ramiah, ati Jesiah, ati Malkiah, ati Miamini, ati Eleasari, ati Malkijah, ati Benaiah. Ati ninu awọn ọmọ Elamu; Mattaniah, Sekariah, ati Jehieli, ati Abdi, ati Jeremoti, ati Elijah. Ati ninu awọn ọmọ Sattu; Elioenai, Eliaṣibu, Mattaniah, ati Jeremoti, ati Sabadi, ati Asisa. Ninu awọn ọmọ Bebai pẹlu; Jehohanani, Hananiah, Sabbai ati Atlai. Ati ninu awọn ọmọ Bani; Meṣullamu, Malluki, ati Adaiah, Jaṣubu, ati Ṣeali ati Ramoti. Ati ninu awọn ọmọ Pahat-moabu Adma ati Kelali, Benaiah, Maaseiah, Mattaniah, Besaleeli, ati Binnui, ati Manasse. Ati ninu awọn ọmọ Harimu; Elieseri, Isṣjah, Malkiah, Ṣemaiah, Ṣimeoni, Benjamini, Malluki, ati Ṣemariah. Ninu awọn ọmọ Haṣumu; Mattenai, Mattatta, Sabadi, Elifeleti, Jeremai, Manasse, ati Ṣimei. Ninu awọn ọmọ Bani; Maadai, Amramu ati Ueli. Benaiah, Bedeiah, Kellu, Faniah, Meremoti, Eliaṣibu, Mattaniah, Mattenai ati Jaasau, Ati Bani, ati Binnui, Ṣimei. Ati Ṣelemiah, ati Natani, ati Adaiah, Maknadebai, Saṣai, Ṣarai, Asareeli, ati Ṣelemiah, Ṣemariah. Ṣallumu, Amariah, ati Josefu. Ninu awọn ọmọ Nebo; Jeieli, Mattitiah, Sabadi, Ṣebina, Jadau, ati Joeli, Benaiah. Gbogbo awọn yi li o mu ajeji obinrin ba wọn gbe, omiran ninu wọn si ni obinrin nipa ẹniti nwọn li ọmọ.