Esr 10:18-44

Esr 10:18-44 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa, a ri awọn ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe: ninu awọn ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati awọn arakunrin rẹ̀; Maaseiah, ati Elieseri, ati Jaribi ati Gedaliah. Nwọn si fi ọwọ wọn fun mi pe: awọn o kọ̀ awọn obinrin wọn silẹ; nwọn si fi àgbo kan rubọ ẹ̀ṣẹ nitori ẹbi wọn. Ati ninu awọn ọmọ Immeri; Hanani ati Sebadiah. Ati ninu awọn ọmọ Harimu; Maaseiah, ati Elija, ati Ṣemaiah, ati Jehieli, ati Ussiah. Ati ninu awọn ọmọ Paṣuri; Elioenai, Maaseiah, Iṣmaeli, Nataneeli Josabadi, ati Eleasa. Ati ninu awọn ọmọ Lefi; Josabadi, ati Ṣimei, ati Kelaiah (eyi ni Kelita) Petahiah, Juda, ati Elieseri. Ninu awọn akọrin pẹlu; Eliaṣibu: ati ninu awọn adèna; Ṣallumu, ati Telemi, ati Uri. Pẹlupẹlu ninu Israeli: ninu awọn ọmọ Paroṣi: Ramiah, ati Jesiah, ati Malkiah, ati Miamini, ati Eleasari, ati Malkijah, ati Benaiah. Ati ninu awọn ọmọ Elamu; Mattaniah, Sekariah, ati Jehieli, ati Abdi, ati Jeremoti, ati Elijah. Ati ninu awọn ọmọ Sattu; Elioenai, Eliaṣibu, Mattaniah, ati Jeremoti, ati Sabadi, ati Asisa. Ninu awọn ọmọ Bebai pẹlu; Jehohanani, Hananiah, Sabbai ati Atlai. Ati ninu awọn ọmọ Bani; Meṣullamu, Malluki, ati Adaiah, Jaṣubu, ati Ṣeali ati Ramoti. Ati ninu awọn ọmọ Pahat-moabu Adma ati Kelali, Benaiah, Maaseiah, Mattaniah, Besaleeli, ati Binnui, ati Manasse. Ati ninu awọn ọmọ Harimu; Elieseri, Isṣjah, Malkiah, Ṣemaiah, Ṣimeoni, Benjamini, Malluki, ati Ṣemariah. Ninu awọn ọmọ Haṣumu; Mattenai, Mattatta, Sabadi, Elifeleti, Jeremai, Manasse, ati Ṣimei. Ninu awọn ọmọ Bani; Maadai, Amramu ati Ueli. Benaiah, Bedeiah, Kellu, Faniah, Meremoti, Eliaṣibu, Mattaniah, Mattenai ati Jaasau, Ati Bani, ati Binnui, Ṣimei. Ati Ṣelemiah, ati Natani, ati Adaiah, Maknadebai, Saṣai, Ṣarai, Asareeli, ati Ṣelemiah, Ṣemariah. Ṣallumu, Amariah, ati Josefu. Ninu awọn ọmọ Nebo; Jeieli, Mattitiah, Sabadi, Ṣebina, Jadau, ati Joeli, Benaiah. Gbogbo awọn yi li o mu ajeji obinrin ba wọn gbe, omiran ninu wọn si ni obinrin nipa ẹniti nwọn li ọmọ.

Esr 10:18-44 Yoruba Bible (YCE)

Orúkọ àwọn alufaa tí wọ́n fẹ́ àwọn obinrin àjèjì nìwọ̀nyí: Ninu ìdílé Jeṣua ọmọ Josadaki ati àwọn arakunrin rẹ̀: Maaseaya ati Elieseri, Jaribu, ati Gedalaya. Wọ́n ṣe ìpinnu láti kọ àwọn aya wọn sílẹ̀, wọ́n sì fi àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ninu ìdílé Imeri: Hanani, ati Sebadaya. Ninu ìdílé Harimu: Maaseaya, Elija, Ṣemaaya, Jehieli, ati Usaya. Ninu ìdílé Paṣuri: Elioenai, Maaseaya, Iṣimaeli, Netaneli, Josabadi, ati Elasa. Orúkọ àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n fẹ́ àwọn obinrin àjèjì nìwọ̀nyí: Josabadi, Ṣimei, Kelaya, (tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Kelita), Petahaya, Juda, ati Elieseri. Ninu àwọn akọrin, Eliaṣibu nìkan ni ó fẹ́ obinrin àjèjì. Orúkọ àwọn aṣọ́nà tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì nìwọ̀nyí: Ṣalumu, Telemu, ati Uri. Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì nìwọ̀nyí: Ninu ìdílé Paroṣi: Ramaya, Isaya, ati Malikija; Mijamini, Eleasari, Haṣabaya ati Benaaya. Ninu ìdílé Elamu: Matanaya, Sakaraya, ati Jehieli; Abidi, Jeremotu, ati Elija. Ninu ìdílé Satu: Elioenai, Eliaṣibu, ati Matanaya, Jeremotu, Sabadi, ati Asisa. Ninu ìdílé Bebai: Jehohanani, Hananaya, Sabai, ati Atilai. Ninu ìdílé Bani: Meṣulamu, Maluki, ati Adaaya, Jaṣubu, Ṣeali, ati Jeremotu. Ninu ìdílé Pahati Moabu: Adina, Kelali, ati Benaaya; Maaseaya, Matanaya, ati Besaleli; Binui, ati Manase. Ninu ìdílé Harimu: Elieseri, Iṣija, ati Malikija; Ṣemaaya, ati Ṣimeoni. Bẹnjamini, Maluki ati Ṣemaraya. Ninu ìdílé Haṣumu: Matenai, Matata, ati Sabadi; Elifeleti, Jeremai, Manase, ati Ṣimei. Ninu ìdílé Bani: Maadai, Amramu, ati Ueli; Benaaya, Bedeaya, ati Keluhi; Faniya, Meremoti, ati Eliaṣibu, Matanaya, Matenai ati Jaasu. Ninu ìdílé Binui: Ṣimei, Ṣelemaya, Natani, ati Adaaya, Makinadebai, Ṣaṣai ati Ṣarai, Asareli, Ṣelemaya, ati Ṣemaraya, Ṣalumu, Amaraya, ati Josẹfu. Ninu ìdílé Nebo: Jeieli, Matitaya, Sabadi, Sebina, Jadai, Joẹli, ati Benaaya. Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì ni wọ́n kọ àwọn aya wọn sílẹ̀ tọmọtọmọ.

Esr 10:18-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lára ìran àwọn àlùfáà àwọn wọ̀nyí fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì: Nínú ìran Jeṣua ọmọ Josadaki, àti àwọn arákùnrin rẹ: Maaseiah, Elieseri, Jaribi àti Gedaliah. Gbogbo wọn ni wọ́n ṣe ìpinnu láti lé àwọn ìyàwó wọn lọ, wọ́n sì fi àgbò kan láàrín agbo ẹran lélẹ̀ fún ẹ̀bi wọn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀. Nínú ìran Immeri: Hanani àti Sebadiah. Nínú ìran Harimu: Maaseiah, Elijah, Ṣemaiah, Jehieli àti Ussiah. Nínú ìran Paṣuri: Elioenai, Maaseiah, Iṣmaeli, Netaneli, Josabadi àti Eleasa. Lára àwọn ọmọ Lefi: Josabadi, Ṣimei, Kelaiah (èyí tí í ṣe Kelita), Petahiah, Juda àti Elieseri. Nínú àwọn akọrin: Eliaṣibu. Nínú àwọn aṣọ́nà: Ṣallumu, Telemu àti Uri. Àti lára àwọn ọmọ Israẹli tókù: Nínú ìran Paroṣi: Ramiah, Issiah, Malkiah, Mijamini, Eleasari, Malkiah àti Benaiah. Nínú ìran Elamu: Mattaniah, Sekariah, Jehieli, Abdi, Jerimoti àti Elijah. Nínú àwọn ìran Sattu: Elioenai, Eliaṣibu, Mattaniah, Jerimoti, Sabadi àti Asisa. Nínú àwọn ìran Bebai: Jehohanani, Hananiah, Sabbai àti Atlai. Nínú àwọn ìran Bani: Meṣullamu, Malluki, Adaiah, Jaṣubu, Ṣeali àti Jerimoti. Nínú àwọn Pahati-Moabu: Adma, Kelali, Benaiah, Maaseiah, Mattaniah, Besaleli, Binnui àti Manase. Nínú àwọn ìran Harimu: Elieseri, Iṣiah, Malkiah àti Ṣemaiah, Simeoni, Benjamini, Malluki àti Ṣemariah. Nínú àwọn ìran Haṣumu: Mattenai, Mattatta, Sabadi, Elifaleti, Jeremai, Manase àti Ṣimei. Nínú àwọn ìran Bani: Maadai, Amramu, Ueli, Benaiah, Bediah, Keluhi Faniah, Meremoti, Eliaṣibu, Mattaniah, Mattenai àti Jaasu. Àti Bani, àti Binnui: Ṣimei, Ṣelemiah, Natani, Adaiah, Maknadebai, Sasai, Ṣarai, Asareeli, Ṣelemiah, Ṣemariah, Ṣallumu, Amariah àti Josẹfu. Nínú àwọn ìran Nebo: Jeieli, Mattitiah, Sabadi, Sebina, Jaddai, Joeli àti Benaiah. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ló fẹ́ obìnrin àjèjì, àwọn mìíràn nínú wọn sì bi ọmọ ní ipasẹ̀ àwọn ìyàwó wọ̀nyí.