Esek 9

9
Wọ́n Jẹ Jerusalẹmu Níyà
1O si fi ohùn rara kigbe li eti mi wipe, Mu gbogbo awọn alaṣẹ ilu sunmọ itosi, olukuluku ton ti ohun ija iparun li ọwọ́ rẹ̀.
2Si kiyesi i, ọkunrin mẹfa jade lati ẹnu ilẹkun oke wá, ti o wà niha ariwa, olukuluku ton ti ohun-ijà ipani li ọwọ́ rẹ̀: ọkunrin kan ninu wọn si wọ aṣọ ọgbọ̀, pẹlu ìwo-tàdawa akọwe li ẹgbẹ́ rẹ̀: nwọn si wọ inu ile, nwọn si duro lẹba pẹpẹ idẹ.
3Ogo Ọlọrun Israeli si ti goke kuro lori kerubu, eyi ti o ti wà, si iloro ile. O si pe ọkunrin na ti o wọ aṣọ ọgbọ̀, ti o ni ìwo-tàdawa akọwe li ẹgbẹ́ rẹ̀:
4Oluwa si wi fun u pe, La ãrin ilu já, li ãrin Jerusalemu, ki o si sami si iwaju awọn ọkunrin ti nkẹdùn, ti nwọn si nkigbe nitori ohun irira ti nwọn nṣe lãrin rẹ̀.
5O si sọ fun awọn iyokù li eti mi, pe, Ẹ tẹ̀ le e la ilu lọ, ẹ si ma kọlù: ẹ má jẹ ki oju nyin dasi, bẹ̃ni ẹ máṣe ṣãnu.
6Ẹ pa arugbo ati ọmọde patapata, awọn wundia ati ọmọ kekeke ati obinrin; ṣugbọn ẹ máṣe sunmọ ẹnikan lara ẹniti àmi na wà; ẹ si bẹrẹ lati ibi mimọ́ mi. Bẹ̃ni nwọn bẹrẹ lati ọdọ awọn agbà ti o wà niwaju ile.
7O si wi fun wọn pe, ẹ sọ ile na di aimọ́, ẹ si fi okú kún agbala na: ẹ jade lọ. Nwọn si jade lọ, nwọn si pa enia ni ilu.
8O si ṣe, nigbati nwọn npa wọn, ti a si fi emi silẹ, mo da oju mi bo ilẹ, mo si kigbe, mo si wipe, Oluwa Ọlọrun, iwọ o ha pa gbogbo awọn iyokù Israeli run, nipa dida irúnu rẹ jade sori Jerusalemu?
9O si wi fun mi pe, Aiṣedede ile Israeli ati ti Juda pọ̀ gidigidi, ilẹ na si kún fun ẹjẹ, ilu si kún fun iyi-ẹjọ-po, nitori nwọn wipe, Oluwa ti kọ aiye silẹ, Oluwa kò riran.
10Bi o si ṣe ti emi ni, oju mi kì o dasi, bẹ̃li emi kì o ṣanu, ṣugbọn emi o sán ọ̀na wọn pada si ori wọn.
11Si kiye si i, ọkunrin ti o wọ aṣọ ọ̀gbọ, ti o ni ìwo-tadawa li ẹgbẹ́ rẹ̀ rohìn, wipe, mo ti ṣe gẹgẹ bi o ti paṣẹ fun mi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Esek 9: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀