Esek 10

10
Ògo OLUWA Kúrò Ninu Tẹmpili Náà
1MO si wò, si kiye si i, ninu ofurufu ti o wà loke lori awọn kerubu, ohun kan hàn li ori wọn bi okuta safire bi irí aworan itẹ́.
2O si sọ fun ọkunrin ti o wọ aṣọ ọ̀gbọ, o si wipe, Bọ sarin kẹkẹ, labẹ kerubu; si bu ikúnwọ ẹyin iná lati agbedemeji awọn kerubu; si fọ́n wọn ka sori ilu na. O si wọ inu ile li oju mi.
3Awọn kerubu si duro li apá ọtun ile na, nigbati ọkunrin na wọ ile; awọ sanma si kún agbala ti inu.
4Ogo Oluwa si goke lọ kuro lori kerubu o si duro loke iloro ile na; ile na si kún fun awọsanma, agbala na si kùn fun didán ogo Oluwa.
5A si gbọ́ iró iyẹ awọn kerubu titi de agbala ode, bi ohùn Ọlọrun Oludumare nigbati o nsọ̀rọ.
6O si ṣe, nigbati o ti paṣẹ fun ọkunrin ti o wọ aṣọ ọgbọ, wipe, Fọn iná lati ãrin awọn kẹkẹ, lati ãrin awọn kerubu, o si wọ inu ile, o si duro lẹba awọn kẹkẹ.
7Kerubu kan si nà ọwọ́ rẹ̀ jade lati ãrin awọn kerubu si iná ti o wà li ãrin awọn kerubu, o si mu ninu rẹ̀, o si fi si ọwọ́ ẹniti o wọ aṣọ ọgbọ̀: ẹniti o gbà a; ti o si jade lọ.
8Aworan ọwọ́ enia si hàn ninu awọn kerubu labẹ iyẹ́ wọn.
9Nigbati mo si wò, kiye si i, awọn kẹkẹ mẹrin na niha awọn kerubu, kẹkẹ kan niha kerubu kan, ati kẹkẹ miran niha kerubu miran; irí awọn kẹkẹ na si dabi awọ̀ okuta berili.
10Bi o si ṣe ti irí wọn, awọn mẹrẹrin ni aworan kanna, bi ẹnipe kẹkẹ́ kan ti wà li ãrin kẹkẹ́ kan.
11Nigbati nwọn lọ, nwọn fi ihà wọn mẹrẹrin lọ, nwọn kò yipada bi nwọn ti nlọ, ṣugbọn ibi ti ori ba kọju si, nwọn a tẹle e; nwọn kò yipada bi nwọn ti nlọ.
12Ati gbogbo ara wọn, ati ẹhìn wọn, ati ọwọ́ wọn ati iyẹ́ wọn, ati awọn kẹkẹ́, kún fun oju yika kiri kẹkẹ́, ti awọn mẹrẹrin ni.
13Niti awọn kẹkẹ́, a ke si wọn li etí mi wipe, Kẹkẹ́!
14Olukuluku wọn si ni oju mẹrin, oju ekini oju kerubu, oju keji, oju enia, ati ẹkẹta oju kiniun, ati ẹkẹrin oju idi.
15A si gbe awọn kerubu soke, eyi ni ẹda alãye ti mo ri lẹba odò Kebari.
16Nigbati awọn kerubu si lọ, awọn kẹkẹ lọ li ẹgbẹ́ wọn: nigbati awọn kerubu si gbe iyẹ́ wọn soke lati fò soke kuro lori ilẹ, kẹkẹ́ kanna kò yipada kuro li ẹgbẹ́ wọn.
17Nigbati nwọn duro, wọnyi duro; nigbati a si gbe wọn soke, wọnyi gbe ara wọn soke pẹlu; nitori ẹmi ẹda alãye na mbẹ ninu wọn.
18Ogo Oluwa si lọ kuro ni iloro ile na, o si duro lori awọn kerubu.
19Awọn kerubu si gbe iyẹ́ wọn soke, nwọn si fò kuro lori ilẹ li oju mi: nigbati nwọn jade lọ, awọn kẹkẹ wà li ẹgbẹ̀ wọn pẹlu, olukuluku si duro nibi ilẹkun ẹnu-ọ̀na ilà-õrun ile Oluwa: ogo Ọlọrun Israeli si wà lori wọn loke.
20Eyi ni ẹda alãye ti mo ri labẹ Ọlọrun Israeli li ẹba odò Kebari, mo si mọ̀ pe kerubu ni nwọn.
21Olukuluku wọn ni oju mẹrin li ọkankan, olukuluku wọn si ni iyẹ́ mẹrin; ati aworan ọwọ́ enia wà li abẹ iyẹ́ wọn.
22Aworan oju wọn si jẹ oju kanna ti mo ri lẹba odò Kebari, iri wọn ati awọn tikara wọn: olukuluku wọn lọ li ọkankan ganran.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Esek 10: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀