Esek 39

39
1NITORINA, iwọ ọmọ enia, sọtẹlẹ si Gogu, si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiye si i, emi dojukọ́ ọ, iwọ Gogu, olori ọmọ-alade Meṣeki ati Tubali:
2Emi o si dá ọ padà, emi o si dári rẹ, emi o si mu ọ goke wá lati ihà ariwa, emi o si mu ọ wá sori oke giga Israeli:
3Emi o si lù ọrun rẹ kurò li ọwọ́ osì rẹ, emi o si mu ọfà rẹ bọ kuro lọwọ ọtun rẹ.
4Iwọ o ṣubu lori òke giga Israeli, iwọ, ati gbogbo awọn ogun rẹ, ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ: emi o fi ọ fun ẹiyẹ ọdẹ onirũru iyẹ, ati ẹranko igbẹ lati pa jẹ.
5Iwọ o ṣubu ni gbangba oko: nitori emi li o sọ ọ, ni Oluwa Ọlọrun wi.
6Emi o si rán iná si Magogu, ati sãrin awọn ti ngbe erekuṣu laibẹ̀ru; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
7Emi o si sọ orukọ mimọ́ mi di mimọ̀ lãrin enia mi Israeli; emi kì yio si jẹ ki nwọn bà orukọ mimọ́ mi jẹ mọ: awọn orilẹ-ède yio si mọ̀ pe emi li Oluwa, Ẹni-Mimọ́ ni Israeli.
8Kiye si i, o ti de, a si ti ṣe e; ni Oluwa Ọlọrun wi, eyi ni ọjọ ti emi ti sọ.
9Awọn ti o si ngbe ilu Israeli yio jade lọ, nwọn o si fi ohun ihamọra wọnni jona ati asa ati apata, ọrun ati ọfà, kùmọ ati ọ̀kọ; nwọn o si fi iná sun wọn li ọdun meje:
10Nwọn kì yio lọ rù igi lati inu oko wá, bẹ̃ni nwọn kì yio ke igi lulẹ lati inu igbẹ́ wá; nitori ohun ihamọra ni nwọn ti fi daná; nwọn o si ko awọn ti o ko wọn, nwọn o si dọdẹ awọn ti o dọdẹ wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.
11Yio si ṣe li ọjọ na, emi o fi ibikan fun Gogu nibẹ fun iboji ni Israeli, afonifoji awọn èro ni gabasi okun; on si pa awọn èro ni ẹnu mọ: nibẹ ni nwọn o gbe sin Gogu ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ si: nwọn o si pè e ni, Afonifoji Hamon-gogu.
12Oṣù meje ni ile Israeli yio si ma fi sin okú wọn, ki nwọn ba le sọ ilẹ na di mimọ́.
13Gbogbo enia ilẹ na ni yio si sin wọn: yio si jẹ okiki fun wọn li ọjọ ti a o yìn mi logo, ni Oluwa Ọlọrun wi.
14Nwọn o si yà awọn ọkunrin sọtọ ti yio ma fi ṣe iṣẹ iṣe, lati ma rìn ilẹ na ja lati lọ isin awọn erò ti o kù lori ilẹ, lati sọ ọ di mimọ́: lẹhin oṣù meje nwọn o ma wá kiri.
15Awọn èro ti nlà ilẹ na kọja, nigbati ẹnikan ba ri egungun enia kan, yio sàmi kan si ẹba rẹ̀, titi awọn asinku yio fi sin i si afonifoji Hamon-gogu.
16Orukọ ilu na pẹlu yio si jẹ Hamona. Bayi ni nwọn o si sọ ilẹ na di mimọ́.
17Ati iwọ, ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Sọ fun olukuluku ẹiyẹ abiyẹ́, ati fun olukuluku ẹranko igbẹ, pe, Ẹ ko ara nyin jọ, ki ẹ si wá: ẹ gbá ara nyin jọ ni ihà gbogbo si ẹbọ mi ti emi rú fun nyin, ani irubọ nla lori oke giga Israeli, ki ẹnyin ba le jẹ ẹran, ki ẹ si mu ẹjẹ.
18Ẹnyin o jẹ ẹran-ara awọn alagbara, ẹnyin o si mu ẹjẹ awọn ọmọ-alade aiye, ti agbò, ti ọdọ agutan, ati ti obukọ, ti akọ malũ, gbogbo wọn abọpa Baṣani.
19Ẹ o si jẹ ọra li ajẹyo, ẹ o si mu ẹjẹ li amupara, lati inu ẹbọ mi ti mo ti rú fun nyin.
20Bayi li a o fi ẹṣin ati ẹlẹṣin bọ́ nyin yo lori tabili mi, pẹlu awọn alagbara, ati gbogbo awọn ologun, ni Oluwa Ọlọrun wi.
21Emi o si gbe ogo mi kalẹ lãrin awọn keferi, gbogbo awọn keferi yio si ri idajọ mi ti mo ti ṣe, ati ọwọ́ mi ti mo ti fi le wọn.
22Ile Israeli yio si mọ̀ pe, Emi li Oluwa Ọlọrun wọn lati ọjọ na lọ titi.
23Awọn keferi yio si mọ̀ pe Israeli lọ si igbekùn nitori aiṣedẽde wọn: nitoriti nwọn ti ṣọ̀tẹ si mi, nitorina ni mo ṣe fi oju mi pamọ kuro lọdọ wọn, ti mo si fi wọn le awọn ọta wọn lọwọ: gbogbo wọn si ti ipa idà ṣubu.
24Gẹgẹ bi aimọ́ wọn, ati gẹgẹ bi irekọja wọn ni mo ṣe si wọn, mo si fi oju mi pamọ́ kuro lọdọ wọn.
25Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nisisiyi li emi o mu igbèkun Jakobu padà bọ̀, emi o si ṣãnu fun gbogbo ile Israeli, emi o si jowu nitori orukọ mi mimọ́:
26Nwọn o si rù itiju wọn, ati gbogbo ọ̀tẹ wọn ti nwọn ti ṣe si mi, nigbati nwọn ngbe laibẹ̀ru ni ilẹ wọn, ti ẹnikẹni kò si dẹ̀ruba wọn.
27Nigbati emi ti mu wọn bọ̀ lati ọdọ orilẹ-ède, ti mo si ko wọn jọ lati ilẹ awọn ọta wọn wá, ti a si yà mi si mimọ́ ninu wọn niwaju orilẹ-ède pupọ.
28Nigbana ni nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun wọn, nipa kikó ti mo mu ki a kó wọn lọ si igbekun lãrin awọn keferi: ṣugbọn mo ti ṣà wọn jọ si ilẹ wọn, emi kò si fi ẹnikẹni wọn silẹ nibẹ mọ.
29Emi kì yio si fi oju mi pamọ kuro lọdọ wọn mọ: nitori emi ti tú ẹmi mi sori ile Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Esek 39: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀