Nigbana ni emi o fi omi mimọ́ wọ́n nyin, ẹnyin o si mọ́: emi o si wẹ̀ nyin mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin nyin ati kuro ninu gbogbo oriṣa nyin.
Emi o fi ọkàn titun fun nyin pẹlu, ẹmi titun li emi o fi sinu nyin, emi o si mu ọkàn okuta kuro lara nyin, emi o si fi ọkàn ẹran fun nyin.
Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, emi o si mu ki ẹ ma rìn ninu aṣẹ mi, ẹnyin o pa idajọ mi mọ, ẹ o si ma ṣe wọn.
Ẹnyin o si ma gbe ilẹ ti emi fi fun awọn baba nyin; ẹnyin o si ma jẹ enia mi, emi o si ma jẹ Ọlọrun nyin.
Emi o si gbà nyin là kuro ninu aimọ́ nyin gbogbo: emi o si pè ọkà wá, emi o si mu u pọ̀ si i, emi kì yio si mu ìyan wá ba nyin.
Emi o si sọ eso-igi di pupọ̀, ati ibísi oko, ki ẹ má bà gbà ẹ̀gan ìyan mọ lãrin awọn keferi.
Nigbana li ẹnyin o ranti ọ̀na buburu nyin, ati iṣe nyin ti kò dara, ẹ o si sú ara nyin li oju ara nyin fun aiṣedẽde nyin, ati fun irira nyin.
Kì iṣe nitori ti nyin li emi ṣe eyi, ni Oluwa Ọlọrun wi, ẹ mọ̀ eyi: ki oju ki o tì nyin, ki ẹ si dãmú nitori ọ̀na ara nyin, ile Israeli.
Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Li ọjọ ti emi o ti wẹ̀ nyin mọ́ kuro ninu aiṣedẽde nyin gbogbo, emi o mu ki a tun gbe ilu, a o si kọ́ ibi ahoro wọnni.
Ilẹ ahoro li a o si ro, ti o ti di ahoro li oju gbogbo awọn ti o ti kọja.
Nwọn o si wipe, Ilẹ yi ti o ti di ahoro ti dabi ọgbà Edeni; ati ilu ti o tú, ti o di ahoro, ti o si parun, di ilu olodi, o si ni olugbe.
Nigbana ni awọn keferi iyokù yika nyin yio mọ̀ pe emi Oluwa ti kọ́ ilu ti o parun, emi si ti gbìn eyiti o ti di ahoro: emi Oluwa ti sọ ọ, emi o si ṣe e.