Esek 26
26
1O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣu ikini, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,
2Ọmọ enia, nitoriti Tire ti sọ̀rọ si Jerusalemu, pe, Aha, a fọ́ eyiti iṣe bode awọn orilẹ-ède: a yi i pada si mi, emi o di kikún, on di ahoro:
3Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; kiyesi i, mo doju kọ ọ, iwọ Tire, emi o si jẹ ki orilẹ-ède pupọ dide si ọ, gẹgẹ bi okun ti igbé ríru rẹ̀ soke.
4Nwọn o si wó odi Tire lulẹ, nwọn o si wó ile iṣọ́ rẹ̀ lulẹ; emi o si há erùpẹ rẹ̀ kuro lara rẹ̀, emi o si ṣe e bi ori apata.
5Yio jẹ ibi ninà awọ̀n si lãrin okun: nitori mo ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi: yio si di ikogun fun awọn orilẹ-ède.
6Ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ ti o wà li oko, li a o fi idà pa; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
7Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o mu Nebukadnessari ọba Babiloni, ọba awọn ọba, wá si Tire, lati ariwa, pẹlu ẹṣin, ati kẹkẹ́ ogun, ati ẹlẹṣin, ati ẹgbẹ́, ati enia pupọ.
8Yio fi idà pa awọn ọmọbinrin rẹ li oko: yio si kọ kũkũ tì ọ, yio si mọ odi tì ọ, yio si gbe apata soke si ọ.
9Yio si gbe ohun-ẹrọ ogun tì odi rẹ, yio si fi ãke rẹ̀ wó ile-iṣọ́ rẹ lulẹ.
10Nitori ọ̀pọ awọn ẹṣin rẹ̀ ẽkuru wọn yio bò ọ: odi rẹ yio mì nipa ariwo awọn ẹlẹṣin, ati kẹkẹ́, ati kẹkẹ́ ogun, nigbati yio wọ̀ inu odi rẹ lọ, gẹgẹ bi enia ti wọ̀ inu ilu ti a fọ́.
11Pátakò ẹṣin rẹ̀ ni yio fi tẹ̀ gbogbo ìta rẹ mọlẹ: on o fi idà pa awọn enia rẹ, ati ọwọ̀n lile rẹ yio wó lulẹ.
12Nwọn o si fi ọrọ̀ rẹ ṣe ikogun, ati òwo rẹ ṣe ijẹ ogun; nwọn o si wo odi rẹ lulẹ, nwọn o si bà ile rẹ daradara jẹ: nwọn o si ko okuta rẹ, ati ìti igi-ìkọle rẹ, ati erùpẹ rẹ, dà si ãrin omi.
13Emi o si mu ariwo orin rẹ dakẹ; ati iró dùru rẹ li a kì yio gbọ́ mọ.
14Emi o si ṣe ọ bi ori apáta; iwọ o si jẹ ibi lati nà awọ̀n le lori; a kì yio kọ́ ọ mọ: nitori emi Oluwa li o ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi.
15Bayi li Oluwa Ọlọrun wi si Tire; awọn erekùṣu kì yio ha mì-titi nipa iró iṣubu rẹ, nigbati awọn ti o gbọgbẹ́ kigbe, nigbati a ṣe ipani li ãrin rẹ?
16Nigbana li awọn ọmọ-alade okun yio sọ̀kalẹ kuro lori itẹ́ wọn, nwọn o si pa aṣọ igunwà wọn tì, nwọn o si bọ́ ẹ̀wu oniṣẹ-ọnà wọn: nwọn o fi ìwariri bò ara wọn; nwọn o joko lori ilẹ, nwọn o si warìri nigba-gbogbo, ẹnu o si yà wọn si ọ.
17Nwọn o si pohunrere-ẹkun fun ọ, nwọn o si wi fun ọ pe, Bawo li ati pa ọ run, iwọ ti awọn èro okun ti ngbe inu rẹ̀, ilu olokikí, ti o lagbara li okun, on ati awọn ti o gbe inu rẹ̀, ẹniti o mu ẹ̀ru wọn wá sara gbogbo awọn ti o pàra ninu rẹ!
18Nisisiyi ni awọn erekùṣu yio warìri li ọjọ iṣubu rẹ; nitõtọ, awọn erekùṣu ti o wà ninu okun li a o yọ lẹnu nigba atilọ rẹ.
19Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nigbati emi o sọ ọ di ahoro ilu, gẹgẹ bi ilu wọnni ti a kò gbe inu wọn; nigbati emi o si mu ibú wá sori rẹ, ati omi nla yio si bò ọ.
20Nigbati emi o bá mu ọ walẹ pẹlu awọn ti o sọkalẹ sinu ihò, pẹlu awọn enia igbãni, ti emi o si gbe ọ kà ibi isalẹ ilẹ aiye, ni ibi ahoro igbãni, pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò, ki a máṣe gbe inu rẹ mọ́: emi o si gbe ogo kalẹ ni ilẹ awọn alãye;
21Emi o si ṣe ọ ni ẹ̀ru, iwọ kì yio si si mọ́: bi a tilẹ wá ọ, sibẹ a kì yio tun ri ọ mọ́, li Oluwa Ọlọrun wi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Esek 26: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.