Esek 24
24
1Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, li ọdun kẹsan, li oṣu kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣu, wipe,
2Ọmọ enia, iwọ kọ orukọ ọjọ na, ani ọjọ kanna yi: ọba Babiloni doju kọ Jerusalemu li ọjọ kanna yi:
3Si pa owe si ọlọtẹ ilẹ na, si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Gbe ìkoko ka iná, gbe e kà a, si dà omi sinu rẹ̀ pẹlu:
4Kó aján na jọ sinu rẹ̀, olukuluku aján ti o tobi, itan, ati apá, fi egungun ti o jọju kún inu rẹ̀.
5Mu ninu agbo-ẹran ti o jọju, ko awọn egungun sabẹ rẹ̀, si jẹ ki o hó dãdã, si jẹ ki nwọn bọ̀ egungun rẹ̀ ninu rẹ̀.
6Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Egbé ni fun ilu ẹlẹjẹ na, fun ìkoko ti ifõfo rẹ̀ wà ninu rẹ̀, ti ifõfo rẹ̀ kò dá loju rẹ̀: mu u jade li aján li aján; máṣe dìbo nitori rẹ̀.
7Nitori ẹjẹ rẹ̀ wà lãrin rẹ̀, o gbé e kà ori apata kan, kò tú u dà sori ilẹ, lati fi erupẹ bò o.
8Ki o ba lè jẹ ki irúnu ki o de, lati gbẹsan; mo ti gbe ẹjẹ rẹ̀ kà ori apata kan, ki a má ba le bò o.
9Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Egbe ni fun ilu ẹlẹjẹ na! Emi o tilẹ jẹ ki òkiti iná na tobi.
10Ko igi jọ si i, ko iná jọ, jo ẹran na, fi turari dùn u; si jẹ ki egungun na jona.
11Si gbe e kà ori ẹyín iná na lasan, ki idẹ rẹ̀ le gbona, ki o le pọ́n, ati ki ẽri rẹ̀ le di yiyọ́ ninu rẹ̀, ki ifõfo rẹ̀ le run.
12On ti fi eke dá ara rẹ̀ lagara, ifõfo nla rẹ̀ kò si jade kuro lara rẹ̀ ifõfo rẹ̀ yio wà ninu iná.
13Ninu ẽri rẹ̀ ni iwà ifẹkufẹ wà: nitori mo ti wẹ̀ ọ, iwọ kò si mọ́, a kì yio si tun wẹ̀ ọ kuro ninu ẽri rẹ mọ, titi emi o fi jẹ ki irúnu mi ba le ọ lori.
14Emi Oluwa li o ti sọ ọ, yio si ṣẹ, emi o si ṣe e: emi kì yio pada sẹhìn, bẹ̃ni emi kì yio dasi, bẹ̃ni emi kì yio ronupiwada; gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, ati gẹgẹ bi iṣe rẹ ni nwọn o da ọ lẹjọ, li Oluwa Ọlọrun wi.
15Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
16Ọmọ enia, kiye si i, mo mu ifẹ oju rẹ kuro lọdọ rẹ, nipa lilù kan: ṣugbọn iwọ kò gbọdọ gbãwẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sọkun, bẹ̃ni omije rẹ kò gbọdọ ṣan silẹ.
17Máṣe sọkun, máṣe gbãwẹ fun okú, wé lawàni sori rẹ, si bọ̀ bata rẹ si ẹsẹ rẹ, máṣe bò ète rẹ, máṣe jẹ onjẹ enia.
18Bẹ̃ni mo sọ fun awọn enia li owurọ: li aṣálẹ obinrin mi si kú, mo si ṣe li owurọ bi a ti pá a li aṣẹ fun mi.
19Awọn enia si sọ fun mi wipe, Iwọ kì yio ha sọ fun wa ohun ti nkan wọnyi jasi fun wa, ti iwọ ṣe bayi?
20Mo si da wọn lohùn pe, Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe,
21Sọ fun ile Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, kiyesi i emi o sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́, titayọ agbara nyin, ifẹ oju nyin, ikãnu ọkàn nyin, ati ọmọ nyin ọkunrin ati ọmọ nyin obinrin, ti ẹnyin ti fi silẹ, yio ti ipa idà ṣubu.
22Ẹnyin o si ṣe bi emi ti ṣe: ẹnyin kò ni bò ète nyin, bẹ̃ni ẹ kò ni jẹ onjẹ enia.
23Lawani nyin yio si wà li ori nyin, ati bàta nyin li ẹsẹ nyin: ẹnyin kò ni gbãwẹ, bẹ̃ni ẹ kò ni sọkun: ṣugbọn ẹnyin o ma joro nitori aiṣedẽde nyin, ẹ o si ma ṣọ̀fọ ẹnikan si ẹnikeji.
24Bayi ni Esekieli jẹ àmi fun nyin: gẹgẹ bi gbogbo ohun ti o ṣe, li ẹ o si ṣe nigbati eyi bá si de, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun:
25Pẹlupẹlu, iwọ ọmọ enia, kì yio ha ṣe pe, ni ijọ na nigbati mo ba gbà agbara wọn, ayọ̀ ogo wọn, ifẹ oju wọn, ati eyiti nwọn gbe ọkàn wọn le, ọmọ wọn ọkunrin, ati ọmọ wọn obinrin, kuro lọdọ wọn,
26Ti ẹniti ti o ba sálà nijọ na, yio tọ̀ ọ wá, lati jẹ ki iwọ ki o fi eti ara rẹ gbọ́?
27Li ọjọ na li ẹnu rẹ yio ṣi si ẹni ti o sala, iwọ o si sọ̀rọ, iwọ kì yio si yadi mọ: iwọ o si jẹ àmi fun wọn; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Esek 24: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.