Esek 23
23
1Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
2Ọmọ enia, obinrin meji wà, ọmọbinrin iyá kanna:
3Nwọn si ṣe panṣaga ni Egipti; nwọn ṣe panṣaga nigba ewe wọn: nibẹ ni a tẹ̀ ọmú wọn, nibẹ ni wọn si rin ọmú igbà wundia wọn.
4Orukọ wọn si ni Ahola, ti iṣe ẹ̀gbọn, ati Aholiba aburo rẹ̀: ti emi si ni nwọn, nwọn si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin. Orukọ wọn ni eyi; Samaria ni Ahola, Jerusalemu si li Aholiba.
5Ahola si ṣe panṣaga, nigbati o jẹ ti emi; o si fẹ awọn olufẹ rẹ̀ li afẹju, awọn ara Assiria aladugbo rẹ̀,
6Ti a fi aṣọ alaro bò lara, awọn balogun ati awọn olori, gbogbo nwọn jẹ ọmọkunrin ti o wun ni, awọn ẹlẹṣin ti o ngùn ẹṣin.
7Bayi li o ṣe panṣaga rẹ̀ pẹlu wọn, pẹlu gbogbo awọn aṣàyan ọkunrin Assiria, ati pẹlu gbogbo awọn ti o fẹ li afẹjù: o fi gbogbo oriṣa wọn ba ara rẹ̀ jẹ.
8Bẹ̃ni kò fi panṣaga rẹ̀ ti o mu ti Egipti wá silẹ: nitori nigba ewe rẹ̀ ni nwọn ba a sùn, nwọn si rin ọmú ìgba wundia rẹ̀, nwọn si dà panṣaga wọn si i lara.
9Nitorina ni mo ti fi le ọwọ́ awọn olufẹ rẹ̀, le ọwọ́ awọn ara Assiria, awọn ti o fẹ li afẹju.
10Awọn wọnyi tu ìhoho rẹ̀ silẹ: nwọn mu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, nwọn si fi idà pa a: o si di ẹni-olokiki lãrin awọn obinrin; nitori pe nwọn ti mu idajọ ṣẹ si i lara.
11Nigbati Aholiba aburo ri eyi, o wà bàjẹ ju on lọ ni ìwa ifẹkufẹ rẹ̀, ati ni panṣaga rẹ̀ ju ẹ̀gbọn rẹ̀ lọ ni panṣaga rẹ̀.
12O fẹ awọn ara Asiria aludugbo rẹ̀ li afẹju, awọn balogun ati awọn olori, ti a wọ̀ li aṣọ daradara, awọn ẹlẹṣin ti o ngùn ẹṣin, gbogbo wọn jẹ ọmọkunrin ti o wuni.
13Nigbana ni mo ri pe a bà a jẹ, awọn mejeji gba ọ̀na kan.
14Ati pe o mu ki panṣaga rẹ̀ bi si i: nitori igbati o ri awọn ọkunrin ti a ṣe li àworan sara ogiri, ere awọn ara Kaldea ti a fi ododó ṣe li àworan,
15Ti a dì li àmure li ẹ̀gbẹ, ti nwọn ṣe aṣejù ni rirẹ lawani ori wọn, gbogbo wọn jẹ ajagun-kẹkẹ́ ti a ba ma wò, gẹgẹ bi iṣe awọn ara Babiloni ti Kaldea, ilẹ ibi wọn:
16Bi o si ti fi oju rẹ̀ ri wọn, o fẹ wọn li afẹjù, o si ran onṣẹ si wọn si Kaldea.
17Awọn ara Babiloni si tọ̀ ọ wá lori akete ifẹ, nwọn si fi panṣaga wọn bà a jẹ, a si bà a jẹ pẹlu wọn, ọkàn rẹ̀ si ṣi kuro lọdọ wọn.
18Bayi li o tú idi panṣaga rẹ̀ silẹ, o si tú ihòho rẹ̀ silẹ: nigbana li ọkàn mi ṣi kuro lọdọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọkàn mi ti ṣi kuro lọdọ ẹ̀gbọn rẹ̀.
19Sibẹsibẹ o mu panṣaga rẹ̀ bi si i ni pipè ọjọ ewe rẹ̀ si iranti, ninu eyi ti o ti ṣe panṣaga ni ilẹ Egipti.
20Nitoripe o fẹ awọn olufẹ wọn li afẹju, ẹran-ara awọn ti o dabi ẹran-ara kẹtẹkẹtẹ, ati irú awọn ẹni ti o dabi irú ẹṣin.
21Bayi ni iwọ pe ìwa ifẹkufẹ ìgba ewe rẹ wá si iranti, niti ririn ori ọmú rẹ lati ọwọ́ awọn ara Egipti, fun ọmú ìgba ewe rẹ.
22Nitorina, iwọ Aholiba, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiye si i, emi o gbe awọn olufẹ rẹ dide si ọ, lọdọ awọn ti ọkàn rẹ ti ṣi, emi o si mu wọn doju kọ ọ niha gbogbo.
23Awọn ara Babiloni, ati gbogbo awọn ara Kaldea, Pekodu, ati Ṣoa, ati Koa, ati gbogbo awọn ara Assiria pẹlu wọn: gbogbo wọn jẹ ọmọkunrin ti o wunni, balogun ati awọn olori, awọn ọkunrin ti o li okiki, gbogbo wọn li o ngun ẹṣin.
24Nwọn o si wá fi kẹkẹ́ ogun, kẹkẹ́ ẹrù, ati kekẹ́ kekeke doju kọ ọ, ati pẹlu ìgbajọ ọ̀pọ enia, awọn ti yio doju asà, ati apata, ati akoro kọ ọ niha gbogbo: emi o si gbe idajọ kalẹ niwaju wọn, nwọn o si da ọ lẹjọ gẹgẹ bi idajọ wọn.
25Emi o si doju owu mi kọ ọ, nwọn o si fi irúnu ba ọ lò: nwọn o fá imu rẹ ati eti rẹ; ati awọn ti o kù ninu rẹ yio ti ọwọ́ idà ṣubu: nwọn o mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ obinrin lọ, ati awọn ti o kù ninu rẹ, li a o fi iná run.
26Nwọn o si bọ aṣọ rẹ, nwọn o si mu ohun ọṣọ daradara rẹ lọ.
27Bayi li emi o jẹ ki ifẹkufẹ rẹ mọ kuro lọdọ rẹ, ati panṣaga rẹ ti o mu ti ilẹ Egipti wá; tobẹ̃, ti iwọ kì yio gboju rẹ soke si wọn, bẹ̃ni iwọ kì yio si ranti Egipti mọ.
28Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o fi ọ le awọn ti iwọ korira lọwọ, li ọwọ́ awọn ẹniti ọkàn rẹ ṣi:
29Nwọn o si ba ọ lo ilo irira, nwọn o si ko gbogbo iṣẹ rẹ lọ, nwọn o si fi ọ silẹ ni ihoho ati ni goloto: ati ihoho panṣaga rẹ li a o tu silẹ, ti ifẹkufẹ rẹ, ati panṣaga rẹ.
30Emi o ṣe gbogbo nkan wọnyi si ọ, nitori pe iwọ ti bá awọn keferi ṣe agbere lọ, ati pe iwọ ti fi oriṣa wọn bà ara rẹ jẹ́.
31Iwọ ti rìn li ọ̀na ẹ̀gbọn rẹ, nitorina li emi o fi ago rẹ̀ le ọ lọwọ.
32Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ o mu ninu ago ẹ̀gbọn rẹ ti o jin, ti o si tobi: a o fi ọ rẹrin ẹlẹya, a o yọ ṣuti si ọ; o gbà pupọ.
33A o fi ọti pa ọ, a o si fi ikãnu kún ọ, pẹlu ago iyanu ati idahoro, pẹlu ago Samaria ẹ̀gbọn rẹ.
34Iwọ o tilẹ mu u, iwọ o si fi ẹnu fa ọti jade, iwọ o si fọ apãdi na, iwọ o si fà ọmú ara rẹ tu, nitori mo ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi.
35Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe iwọ ti gbagbe mi ti o si ti sọ mi si ẹhìn rẹ, nitorina iwọ rù ifẹkufẹ rẹ pẹlu ati panṣaga rẹ,
36Oluwa tun sọ fun mi pe; Ọmọ enia, iwọ o ha dá Ahola ati Aholiba lẹ́jọ? nitõtọ sọ irira wọn fun wọn;
37Pe, nwọn ti ṣe panṣaga ẹ̀jẹ si mbẹ lọwọ wọn, ati nipasẹ oriṣa wọn ni nwọn ti ṣe panṣaga, nwọn si ti jẹ ki awọn ọmọ wọn, ti nwọn bi fun mi, kọja lãrin iná fun wọn, lati run wọn.
38Eyi ni nwọn si ṣe si mi; nwọn ti bà ibi mimọ́ mi jẹ li ọjọ kanna, nwọn sọ ọjọ isimi mi di aìlọwọ.
39Nitoripe igbati nwọn pa awọn ọmọ wọn fun oriṣa wọn, nigbana ni nwọn wá ni ijọ kanna si ibi mimọ́ mi, lati sọ ọ di àilọwọ; si kiye si i, bayi ni nwọn ṣe lãrin ile mi.
40Ati pẹlupẹlu, ti pe ẹnyin ranṣẹ pè awọn ọkunrin lati okẽre wá, sọdọ awọn ti a ranṣẹ pè; si kiyesi i, nwọn de: fun ẹniti iwọ wẹ̀ ara rẹ, ti o si le tirõ, ti o si fi ohun ọṣọ́ ṣe ara rẹ li ọṣọ́.
41Ti o si joko lori àkete daradara, a si tẹ́ tabili siwaju rẹ̀, lori eyi ti iwọ gbe turari mi ati ororó mi lé.
42Ati ohùn ọ̀pọlọpọ enia, ti nwọn pa rọ́rọ wà lọdọ rẹ̀: ati pẹlu enia lasan li a mu awọn Sabeani lati aginjù wá, ti nwọn fi jufù si apá wọn, ati ade daradara si ori wọn.
43Nigbana ni mo wi fun on ti o gbó ni panṣaga, Nwọn o ha bá a ṣe panṣaga nisisiyi, ati on pẹlu wọn?
44Sibẹsibẹ wọn wọle tọ̀ ọ, bi nwọn ti iwọle tọ̀ obinrin ti nṣe panṣaga: bẹ̃ni nwọn wọle tọ̀ Ahola ati Aholiba, awọn onifẹkufẹ obinrin.
45Ati awọn ọkunrin olododo, nwọn o ṣe idajọ wọn, bi a ti iṣe idajọ awọn àgbere obinrin, ati bi a ti iṣe idajọ awọn obinrin ti o ta ẹjẹ silẹ; nitoripe àgbere ni nwọn, ẹjẹ si wà lọwọ wọn.
46Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o mu ẹgbẹ kan tọ̀ wọn wá, emi o si fi wọn fun wọn lati kó wọn lọ, ati lati bà wọn jẹ.
47Ẹgbẹ na yio si sọ wọn li okuta, nwọn o si fi idà pa wọn; nwọn o pa awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn obinrin, nwọn o si fi iná kun ile wọn.
48Bayi li emi o jẹ ki ìwa ifẹkufẹ mọ lãrin ilẹ na, ki a ba le kọ́ gbogbo obinrin, ki nwọn má bà ṣe bi ifẹkufẹ nyin.
49Nwọn o si san ẹ̀san ìwa ifẹkufẹ nyin si ori nyin, ẹnyin o si rù ẹ̀ṣẹ oriṣa nyin; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Esek 23: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.