Esek 13
13
Ìran Ibi Nípa Àwọn Ọkunrin Wolii Èké
1Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe:
2Ọmọ enia, sọtẹlẹ si awọn woli Israeli ti nsọtẹlẹ, ki o si wi fun awọn ti nti ọkàn ara wọn sọtẹlẹ pe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa;
3Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, egbé ni fun awọn aṣiwere woli, ti nwọn ntẹ̀le ẹmi ara wọn, ti wọn kò si ri nkan!
4Israeli, awọn woli rẹ dabi kọ̀lọkọ̀lọ ni ijù,
5Ẹnyin kò ti goke lọ si ibi ti o ya, bẹ̃ni ẹ kò si tun odi mọ fun ile Israeli lati duro li oju ogun li ọjọ Oluwa.
6Nwọn ti ri asan ati àfọṣẹ eke, pe, Oluwa wi: bẹ̃ni Oluwa kò rán wọn, nwọn si ti jẹ ki awọn ẹlomiran ni ireti pe, nwọn o fi idí ọ̀rọ wọn mulẹ.
7Ẹnyin kò ti ri iran asan, ẹ kò si ti fọ àfọṣẹ eke, ti ẹnyin wipe, Oluwa wi bẹ̃? bẹ̃ni emi kò sọrọ.
8Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ẹnyin ti sọ̀rọ asan, ẹnyin si ti ri eke, nitorina, kiyesi i, mo dojukọ nyin, ni Oluwa wi.
9Ọwọ́ mi yio si wà lori awọn woli, ti nwọn ri asan, ti nwọn si nfọ àfọṣẹ eke; nwọn kì yio si ninu ijọ awọn enia mi, bẹ̃ni a kì yio kọwe wọn sinu iwe ile Israeli; bẹ̃ni nwọn kì yio wọ̀ ilẹ Israeli, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
10Nitori, ani nitori ti nwọn ti tàn awọn enia mi wipe, Alafia; bẹ̃ni kò si alafia, ọkan si mọ ogiri, si kiyesi, awọn miran si nfi amọ̀ ti a kò pò rẹ́ ẹ.
11Wi fun awọn ti nfi amọ̀ aipò rẹ́ ẹ, pe, yio ṣubu; òjo yio rọ̀ pupọ; ati Ẹnyin, yinyín nla, o si bọ́; ẹfũfu lile yio si ya a.
12Kiyesi i, nigbati ogiri na ba wo, a kì yio ha wi fun nyin pe, Rirẹ́ ti ẹnyin rẹ́ ẹ ha dà?
13Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o tilẹ fi ẹfũfu lile ya a ni irúnu mi; òjo yio si rọ̀ pupọ ni ibinu mi, ati yinyin nla ni irúnu mi lati run u.
14Bẹ̃ni emi o wo ogiri ti ẹnyin fi amọ̀ aipò rẹ́ lulẹ, emi o si mu u wá ilẹ, tobẹ̃ ti ipilẹ rẹ̀ yio hàn, yio si ṣubu, a o si run nyin li ãrin rẹ̀: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
15Bayi li emi o mu ibinu mi ṣẹ lori ogiri na, ati lori awọn ti o fi amọ̀ aipò rẹ ẹ, emi o si wi fun nyin pe, Ogiri na kò si mọ ati awọn ti o ti rẹ́ ẹ;
16Eyini ni, awọn woli Israeli, ti nwọn sọtẹlẹ niti Jerusalemu, ti nwọn si ri iran alafia fun u, bẹ̃ni alafia kò si, ni Oluwa Ọlọrun wi.
17Iwọ ọmọ enia, dojukọ awọn ọmọbinrin awọn enia rẹ bẹ̃ gẹgẹ, ti nwọn nsọtẹlẹ lati ọkàn ara wọn wá; ki o si sọtẹlẹ si wọn.
18Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Egbé ni fun awọn obinrin ti nrán tìmtim si gbogbo ìgbọnwọ, ti nwọn sì ndá gèle si ori olukuluku enia lati ṣọdẹ ọkàn! Ẹnyin o ṣọdẹ ọkàn awọn enia mi bi, ẹnyin o si gbà ọkàn ti o tọ̀ nyin wá là bi?
19Ẹnyin o ha si bà mi jẹ lãrin awọn enia mi nitori ikunwọ ọkà bàba, ati nitori òkele onjẹ, lati pa ọkàn ti kì ba kú, ati lati gba awọn ọkàn ti kì ba wà lãye là, nipa ṣiṣeke fun awọn enia mi ti ngbọ́ eke nyin?
20Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, mo dojukọ awọn tìmtim nyin, ti ẹnyin fi nṣọdẹ ọkàn nibẹ lati mu wọn fò, emi o si yà wọn kuro li apá nyin, emi o si jẹ ki awọn ọkàn na lọ, ani awọn ọkàn ti ẹnyin ndọdẹ lati mu fò.
21Gèle nyin pẹlu li emi o ya, emi o si gba awọn enia mi lọwọ nyin, nwọn kì yio si si lọwọ nyin mọ lati ma dọdẹ wọn; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
22Nitoripe eke li ẹnyin fi mu ọkàn awọn olododo kãnu, awọn ẹniti emi kò mu kãnu, ẹnyin si mu ọwọ́ enia buburu le, ki o má ba pada kuro li ọ̀na buburu rẹ̀ nipa ṣiṣe ileri ìye fun u:
23Nitorina ẹnyin kì yio ri asan mọ, ẹ kì yio si ma fọ àfọṣẹ, nitoriti emi o gba awọn enia mi kuro li ọwọ́ nyin, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Esek 13: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.