Eks 5
5
Mose ati Aaroni níwájú Ọba Ijipti
1LẸHIN eyinì ni Mose ati Aaroni wọle, nwọn si wi fun Farao pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le ṣe ajọ fun mi ni ijù.
2Farao si wipe, Tali OLUWA, ti emi o fi gbà ohùn rẹ̀ gbọ́ lati jẹ ki Israeli ki o lọ? Emi kò mọ̀ OLUWA na, bẹ̃li emi ki yio jẹ ki Israeli ki o lọ.
3Nwọn si wipe, Ọlọrun awọn Heberu li o pade wa: awa bẹ̀ ọ, jẹ ki a lọ ni ìrin ijọ́ mẹta si ijù, ki a si rubọ si OLUWA Ọlọrun wa; ki o má ba fi ajakalẹ-àrun tabi idà kọlù wa.
4Ọba Egipti si wi fun wọn pe, Mose ati Aaroni, nitori kili ẹnyin ṣe dá awọn enia duro ninu iṣẹ wọn? ẹ lọ si iṣẹ nyin.
5Farao si wipe, Kiyesi i awọn enia ilẹ yi pọ̀ju nisisiyi, ẹnyin si mu wọn simi kuro ninu iṣẹ wọn.
6Farao si paṣẹ li ọjọ́ na fun awọn akoniṣiṣẹ awọn enia, ati fun awọn olori wọn wipe,
7Ẹnyin kò gbọdọ fun awọn enia na ni koriko mọ́ lati ma ṣe briki, bi ìgba atẹhinwá: jẹ ki nwọn ki o ma lọ ṣà koriko fun ara wọn.
8Ati iye briki ti nwọn ti ima ṣe ni ìgba atẹhinwá, on ni ki ẹnyin bù fun wọn; ẹnyin kò gbọdọ ṣẹ nkan kù kuro nibẹ̀: nitoriti nwọn nṣe imẹlẹ; nitorina ni nwọn ṣe nke wipe, Jẹ ki a lọ rubọ si Ọlorun wa.
9Ẹ jẹ ki iṣẹ ki o wuwo fun awọn ọkunrin na, ki nwọn ki o le ma ṣe lãlã ninu rẹ̀; ẹ má si ṣe jẹ ki nwọn ki o fiyesi ọ̀rọ eke.
10Awọn akoniṣiṣẹ enia na si jade, ati awọn olori wọn, nwọn si sọ fun awọn enia na, pe, Bayi ni Farao wipe, Emi ki yio fun nyin ni koriko mọ́.
11Ẹ lọ, ẹ wá koriko nibiti ẹnyin gbé le ri i: ṣugbọn a ki yio ṣẹ nkan kù ninu iṣẹ nyin.
12Bẹ̃li awọn enia na si tuka kiri ká gbogbo ilẹ Egipti lati ma ṣà idi koriko ni ipò koriko.
13Awọn akoniṣiṣẹ lé wọn ni ire wipe, Ẹ ṣe iṣẹ nyin pé, iṣẹ ojojumọ́ nyin, bi igbati koriko mbẹ.
14Ati awọn olori awọn ọmọ Israeli, ti awọn akoniṣiṣẹ Farao yàn lé wọn, li a nlù, ti a si mbilère pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò ṣe iṣẹ nyin pé ni briki ṣiṣe li ana ati li oni, bi ìgba atẹhinwá?
15Nigbana li awọn olori awọn ọmọ Israeli wá, nwọn si ke tọ̀ Farao wipe, Ẽṣe ti iwọ fi nṣe awọn iranṣẹ rẹ bayi?
16A kò fi koriko fun awọn iranṣẹ rẹ, nwọn si nwi fun wa pe, Ẹ ṣe briki: si kiyesi i, a nlù awọn iranṣẹ rẹ; ṣugbọn lọwọ awọn enia rẹ li ẹbi wà.
17Ṣugbọn on wipe, Ẹnyin ọlẹ, ẹnyin ọlẹ: nitorina li ẹ ṣe wipe, Jẹ ki a lọ ṣẹbọ si OLUWA.
18Njẹ ẹ lọ nisisiyi, ẹ ṣiṣẹ; a ki yio sá fi koriko fun nyin, sibẹ̀ iye briki nyin yio pé.
19Awọn olori awọn ọmọ Israeli si ri pe, ọ̀ran wọn kò li oju, lẹhin igbati a wipe, Ẹ ki o dinkù ninu iye briki nyin ojojumọ́.
20Nwọn si bá Mose on Aaroni, ẹniti o duro lati pade wọn bi nwọn ti nti ọdọ Farao jade wá:
21Nwọn si wi fun wọn pe, Ki OLUWA ki o wò nyin, ki o si ṣe idajọ; nitoriti ẹnyin mu wa di okú-õrùn li oju Farao, ati li oju awọn iranṣẹ rẹ̀, lati fi idá lé wọn lọwọ lati pa wa.
Mose Ráhùn sí OLUWA
22Mose si pada tọ̀ OLUWA lọ, o si wi fun u pe, OLUWA, ẽtiṣe ti o fi ṣe buburu si awọn enia yi bẹ̃? ẽtiṣe ti o fi rán mi?
23Nitori igbati mo ti tọ̀ Farao wá lati sọ̀rọ li orukọ rẹ, buburu li o ti nṣe si awọn enia yi; bẹ̃ni ni gbigbà iwọ kò si gbà awọn enia rẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Eks 5: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.