Eks 38

38
1O SI fi igi ṣittimu ṣe pẹpẹ ẹbọsisun: igbọnwọ marun ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ marun ni ibú rẹ̀; onìha mẹrin ọgbọgba ni; igbọnwọ mẹta si ni giga rẹ̀.
2O si ṣe iwo rẹ̀ si i ni igun rẹ̀ mẹrẹrin; iwo rẹ̀ wà lara rẹ̀: o si fi idẹ bò o.
3O si ṣe gbogbo ohunèlo pẹpẹ na, ìkoko rẹ̀, ọkọ́ rẹ̀, ati awokòto rẹ̀, ati kọkọrọ ẹran rẹ̀, ati awo iná wọnni: gbogbo ohunèlo rẹ̀ li o fi idẹ ṣe.
4O si ṣe àro idẹ fun pẹpẹ na ni iṣẹ àwọn nisalẹ ayiká rẹ̀, dé agbedemeji rẹ̀.
5O si dà oruka mẹrin fun ìku mẹrẹrin àro idẹ na, li àye fun ọpá wọnni.
6O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi idẹ bò wọn.
7O si fi ọpá wọnni sinu oruka ni ìha pẹpẹ na, lati ma fi rù u; o fi apáko ṣe pẹpẹ na li onihò ninu.
8O si fi idẹ ṣe agbada na, o si fi idẹ ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀, ti awojiji ẹgbẹ awọn obinrin ti npejọ lati sìn li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
9O si ṣe agbalá na: ni ìha gusù li ọwọ́ ọtún aṣọ-tita agbalá na jẹ́ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ọgọrun igbọnwọ:
10Opó wọn jẹ́ ogún, ihò-ìtẹbọ idẹ wọn jẹ́ ogún; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.
11Ati fun ìha ariwa ọgọrun igbọnwọ, opó wọn jẹ́ ogún, ati ihò-ìtẹbọ idẹ wọn jẹ́ ogún; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.
12Ati fun ìha ìwọ-õrùn li aṣọ-tita ãdọta igbọnwọ, opó wọn mẹwa, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹwa; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.
13Ati fun ìha ìla-õrùn, si ìha ìla-õrùn ãdọta igbọnwọ.
14Aṣọ-tita apakan jẹ́ igbọnwọ mẹdogun; opó wọn jẹ́ mẹta, ati ihò-ìtẹbọ wọn jẹ́ mẹta.
15Ati fun apa keji: li apa ihin ati li apa ọhún ẹnu-ọ̀na agbalá na, li aṣọ-tita onigbọnwọ mẹdogun wà; opó wọn jẹ́ mẹta, ati ihò-ìtẹbọ wọn jẹ́ mẹta.
16Gbogbo aṣọ-tita agbalá na yiká jẹ́ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ.
17Ati ihò-ìtẹbọ fun opó wọnni jẹ́ idẹ; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà; ati ibori ori wọn jẹ́ fadakà; ati gbogbo opó agbalá na li a fi fadakà gbà li ọjá.
18Ati aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na jẹ́ iṣẹ abẹ́rẹ, aṣọ-alaró, ati elesè-aluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ: ogún igbọnwọ si ni gigùn rẹ̀, ati giga ni ibò rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun, o bá aṣọ-tita agbalá wọnni ṣedede.
19Opó wọn si jẹ́ mẹrin, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ, mẹrin; kọkọrọ wọn jẹ́ fadakà, ati ibori ori wọn ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.
20Ati gbogbo ekàn agọ́ na, ati ti agbalá rẹ̀ yiká jẹ́ idẹ.
21Eyi ni iye agọ́ na, agọ́ ẹrí nì, bi a ti kà wọn, gẹgẹ bi ofin Mose, fun ìrin awọn ọmọ Lefi, lati ọwọ́ Itamari wá, ọmọ Aaroni alufa.
22Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah, si ṣe ohun gbogbo ti OLUWA paṣẹ fun Mose.
23Ati Oholiabu pẹlu rẹ̀, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, alagbẹdẹ, ati ọlọgbọ́n ọlọnà, alaró ati ahunṣọ alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ didara.
24Gbogbo wurà ti a lò si iṣẹ na, ni onirũru iṣẹ ibi mimọ́ nì, ani wurà ọrẹ nì, o jẹ́ talenti mọkandilọgbọ̀n, ati ẹgbẹrin ṣekeli o din ãdọrin, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́.
25Ati fadakà awọn ẹniti a kà ninu ijọ-enia jẹ́ ọgọrun talenti, ati ṣekeli ojidilẹgbẹsan o le mẹdogun, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́:
26Abọ ṣekeli kan li ori ọkunrin kọkan, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́, lori ori olukuluku ti o kọja sinu awọn ti a kà, lati ẹni ogún ọdún ati jù bẹ̃ lọ, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ le ẹgbẹtadilogun o le ãdọjọ enia.
27Ati ninu ọgọrun talenti fadakà na li a ti dà ihò-ìtẹbọ wọnni ti ibi mimọ́, ati ihò-ìtẹbọ ti aṣọ-ikele na, ọgọrun ihò-ìtẹbọ ninu ọgọrun talenti na, talenti ka fun ihò-ìtẹbọ kan.
28Ati ninu ojidilẹgbẹsan ṣekeli o le mẹdogun, o mú ṣe kọkọrọ fun ọwọ̀n wọnni, o si fi i bò ori wọn, o si fi i ṣe ọjá wọn.
29Ati idẹ ọrẹ na jẹ́ ãdọrin talenti, ati egbejila ṣekeli.
30On li o si fi ṣe ihò-ìtẹbọ ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ ati pẹpẹ idẹ na, ati àro idẹ sara rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo pẹpẹ na,
31Ati ihò-ìtẹbọ agbalá, na yikà, ati ìho-ìtẹbọ ẹnu-ọ̀na agbalá, ati gbogbo ekàn agọ́ na, ati gbogbo ekàn agbalà na yikà.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Eks 38: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀