Eks 34:1-10

Eks 34:1-10 YBCV

OLUWA si wi fun Mose pe, Iwọ gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju: emi o si kọ ọ̀rọ walã ti iṣaju, ti iwọ ti fọ́, sara walã wọnyi. Si mura li owurọ̀, ki iwọ ki o si gún òke Sinai wá li owurọ̀, ki o si wá duro niwaju mi nibẹ̀ lori òke na. Ẹnikẹni ki yio si bá ọ gòke wá, ki a má si ṣe ri ẹnikẹni pẹlu li òke na gbogbo; bẹ̃ni ki a máṣe jẹ ki agbo-agutan tabi ọwọ́-ẹran ki o jẹ niwaju òke na. On si gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju; Mose si dide ni kutukutu owurọ̀, o si gún òke Sinai, bi OLUWA ti paṣẹ fun u, o si mú walã okuta mejeji li ọwọ́ rẹ̀. OLUWA si sọkalẹ ninu awọsanma, o si bá a duro nibẹ̀, o si pè orukọ OLUWA. OLUWA si rekọja niwaju rẹ̀, o si nkepè, OLUWA, OLUWA, Olọrun alãnu ati olore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹniti o pọ̀ li ore ati otitọ; Ẹniti o npa ãnu mọ́ fun ẹgbẹgbẹrun, ti o ndari aiṣedede, ati irekọja, ati ẹ̀ṣẹ jì, ati nitõtọ ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijiyà; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn omọ, ati lara awọn ọmọ ọmọ, lati irandiran ẹkẹta ati ẹkẹrin. Mose si yara, o si foribalẹ, o si sìn. On si wipe, Njẹ bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ nisisiyi Oluwa, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki Oluwa ki o ma bá wa lọ; nitori enia ọlọrùn lile ni; ki o si dari aiṣẹdede wa ati ẹ̀ṣẹ wa jì, ki o si fi wa ṣe iní rẹ. On si wipe, Kiyesi i, emi dá majẹmu kan: emi o ṣe ohun iyanu, niwaju gbogbo awọn enia rẹ irú eyiti a kò ti iṣe lori ilẹ gbogbo rí, ati ninu gbogbo orilẹ-ède: ati gbogbo enia ninu awọn ti iwọ wà, nwọn o ri iṣẹ OLUWA, nitori ohun ẹ̀ru li emi o fi ọ ṣe.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa