Eks 33:12-23

Eks 33:12-23 YBCV

Mose si wi fun OLUWA pe, Wò o, iwọ wi fun mi pe, Mú awọn enia wọnyi gòke lọ: sibẹ̀ iwọ kò jẹ ki emi ki o mọ̀ ẹniti iwọ o rán pẹlu mi. Ṣugbọn iwọ wipe, Emi mọ̀ ọ li orukọ, iwọ si ri ore-ọfẹ li oju mi pẹlu. Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, fi ọ̀na rẹ hàn mi nisisiyi, ki emi ki o le mọ̀ ọ, ki emi ki o le ri ore-ọfẹ li oju rẹ: ki o si rò pe orilẹ-ède yi enia rẹ ni. On si wipe, Oju mi yio ma bá ọ lọ, emi o si fun ọ ni isimi. On si wi fun u pe, Bi oju rẹ kò ba bá wa lọ, máṣe mú wa gòke lati ihin lọ. Nipa ewo li a o fi mọ̀ nihinyi pe, emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ani emi ati awọn enia rẹ? ki iha iṣe ni ti pe iwọ mbá wa lọ ni, bẹ̃ni a o si yà wa sọ̀tọ, emi ati awọn enia rẹ, kuro lara gbogbo enia ti o wà lori ilẹ? OLUWA si wi fun Mose pe, Emi o ṣe ohun yi ti iwọ sọ pẹlu: nitoriti iwọ ri ore-ọfẹ li oju mi, emi si mọ̀ ọ li orukọ. O si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ogo rẹ̀ hàn mi. On si wi fun u pe, Emi o mu gbogbo ore mi kọja niwaju rẹ, emi o si pè orukọ OLUWA niwaju rẹ; emi o si ṣe ore-ọfẹ fun ẹniti emi nfẹ ṣe ore-ọfẹ fun, emi o si ṣe ãnu fun ẹniti emi o ṣe ãnu fun. On si wipe, Iwọ kò le ri oju mi: nitoriti kò sí enia kan ti iri mi, ti si yè. OLUWA si wipe, Wò, ibi kan wà lẹba ọdọ mi, iwọ o si duro lori apata: Yio si ṣe, nigbati ogo mi ba nrekọja, emi o fi ọ sinu palapala apata, emi o si fi ọwọ́ mi bò ọ titi emi o fi rekọja: Nigbati emi o mú ọwọ́ mi kuro, iwọ o si ri akẹhinsi mi: ṣugbọn oju mi li a ki iri.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa