Eks 27
27
1IWỌ o si tẹ́ pẹpẹ igi ṣittimu kan, ìna rẹ̀ igbọnwọ marun, ati ìbú rẹ̀ igbọnwọ marun; ìwọn kan ni ìha mẹrẹrin: igbọnwọ mẹta si ni giga rẹ̀.
2Iwọ o si ṣe iwo rẹ̀ si ori igun mẹrẹrin rẹ̀: iwo rẹ̀ yio si wà lara rẹ̀: iwọ o si fi idẹ bò o.
3Iwọ o si ṣe tasà rẹ̀ lati ma gbà ẽru rẹ̀, ati ọkọ́ rẹ̀, ati awokòto rẹ̀ ati kọkọrọ ẹran rẹ̀, ati awo-iná rẹ̀ wọnni: gbogbo ohun-èlo rẹ̀ ni iwọ o fi idẹ ṣe.
4Iwọ o si ṣe oju-àro idẹ fun u ni iṣẹ-àwọn; lara àwọn na ni ki iwọ ki o ṣe oruka mẹrin ni igun mẹrẹrin rẹ̀.
5Iwọ o si fi si abẹ ayiká pẹpẹ na nisalẹ, ki àwọn na ki o le dé idaji pẹpẹ na.
6Iwọ o si ṣe ọpá fun pẹpẹ na, ọpá igi ṣittimu, iwọ o si fi idẹ bò wọn.
7A o si fi ọpá rẹ̀ bọ̀ oruka wọnni, ọpá wọnni yio si wà ni ìha mejeji pẹpẹ na, lati ma fi rù u.
8Onihò ninu ni iwọ o fi apáko ṣe e: bi a ti fihàn ọ lori oke, bẹ̃ni ki nwọn ki o ṣe e.
9Iwọ o si ṣe agbalá agọ́ na: ni ìha gusù lọwọ ọtún li aṣọ-tita agbalá ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ti ọgọrun igbọnwọ ìna, yio wà ni ìha kan:
10Ati ogún opó rẹ̀, ati ogún ihò-ìtẹbọ wọn, ki o jẹ́ idẹ; ikọ́ opó wọnni ati ọpá isopọ̀ wọn ki o jẹ́ fadakà.
11Ati bẹ̃ gẹgẹ niti ìha ariwa ni gigùn aṣọ-tita wọnni yio jẹ́ ọgọrun igbọnwọ ni ìna wọn, ati ogún opó rẹ̀, ati ogún ihò-ìtẹbọ rẹ̀ ki o jẹ́ idẹ; ikọ́ opó wọnni ati ọpá isopọ̀ wọn ki o jẹ́ fadakà.
12Ati niti ibú agbalá na, ni ìha ìwọ-õrùn li aṣọ-tita ãdọta igbọnwọ yio wà: opó wọn mẹwa, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹwa.
13Ati ibú agbalá na ni ìha ìla-õrùn si ìha ìla-õrùn yio jẹ́ ãdọta igbọnwọ.
14Aṣọ-tita apakan ẹnu-ọ̀na na yio jẹ́ igbọnwọ mẹdogun: opó wọn mẹta, ihò-ìtẹbọ wọn mẹta.
15Ati ni ìha keji ni aṣọ-tita igbọnwọ mẹdogun yio wà: opó wọn mẹta, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹta.
16Ati fun ẹnu-ọ̀na agbalá na aṣọ-tita ogún igbọnwọ yio wà, ti aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti a fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe: opó wọn mẹrin, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹrin.
17Gbogbo opó ti o yi sarè na ká li a o si fi ọpá fadakà sopọ̀; ikọ́ wọn yio jẹ́ fadakà, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ.
18Ìna agbalá na ki o jẹ́ ọgọrun igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ arãdọtọta igbọnwọ, ati giga rẹ̀ igbọnwọ marun, ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ.
19Gbogbo ohun-èlo agọ́ na, ni gbogbo ìsin rẹ̀, ati gbogbo ekàn rẹ̀, ati gbogbo ekàn agbalá na ki o jẹ́ idẹ.
20Iwọ o si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o mú oróro olifi daradara ti a gún fun ọ wá, fun imọlẹ, lati mu ki fitila ki o ma tàn nigbagbogbo.
21Li agọ́ ajọ lẹhin ode aṣọ-ikele ti o wà niwaju ẹ̀rí na, Aaroni ti on ti awọn ọmọ rẹ̀ ni yio tọju rẹ̀ lati alẹ titi di owurọ̀ niwaju OLUWA: yio si di ìlana lailai ni irandiran wọn lọdọ awọn ọmọ Israeli.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Eks 27: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.