Eks 24

24
1O SI wi fun Mose pe, Goke tọ̀ OLUWA wá, iwọ, ati Aaroni, Nadabu, ati Abihu, ati ãdọrin ninu awọn àgba Israeli; ki ẹnyin ki o si ma sìn li òkere rére.
2Mose nikanṣoṣo ni yio si sunmọ OLUWA; ṣugbọn awọn wọnyi kò gbọdọ sunmọ tosi; bẹ̃li awọn enia kò gbọdọ bá a gòke lọ.
3Mose si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ OLUWA, ati gbogbo idajọ fun awọn enia: gbogbo enia si fi ohùn kan dahùn wipe, Gbogbo ọ̀rọ ti OLUWA wi li awa o ṣe.
4Mose si kọwe gbogbo ọ̀rọ OLUWA, o si dide ni kùtukutu owurọ̀, o si tẹ́ pẹpẹ kan nisalẹ òke na, o mọ ọwọ̀n mejila, gẹgẹ bi ẹ̀ya Israeli mejila.
5O si rán awọn ọdọmọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, nwọn si ru ẹbọ sisun, nwọn si fi akọmalu ru ẹbọ alafia si OLUWA.
6Mose si mú àbọ ẹ̀jẹ na o si fi i sinu awokòto; ati àbọ ẹ̀jẹ na o fi wọ́n ara pẹpẹ na.
7O si mú iwé majẹmu nì, o si kà a li eti awọn enia: nwọn si wipe, Gbogbo eyiti OLUWA wi li awa o ṣe, awa o si gbọràn.
8Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si wọ́n ọ sara awọn enia, o si wipe, Kiyesi ẹ̀jẹ majẹmu, ti OLUWA bá nyin dá nipasẹ ọ̀rọ gbogbo wọnyi.
9Nigbana ni Mose, ati Aaroni, Nadabu, ati Abihu, ati ãdọrin ninu awọn àgba Israeli gòke lọ:
10Nwọn si ri Ọlọrun Israeli; bi iṣẹ okuta Safire wà li abẹ ẹsẹ̀ rẹ̀, o si dabi irisi ọrun ni imọ́toto rẹ̀.
11Kò si nà ọwọ́ rẹ̀ lé awọn ọlọlá ọmọ Israeli: nwọn si ri Ọlọrun, nwọn si jẹ, nwọn si mu.
12OLUWA si wi fun Mose pe, Gòke tọ̀ mi wá sori òke, ki o si duro nibẹ̀; emi o si fi walã okuta fun ọ, ati aṣẹ kan, ati ofin ti mo ti kọ, ki iwọ ki o le ma kọ́ wọn.
13Mose si dide, ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀: Mose si gòke lọ si oke Ọlọrun.
14O si wi fun awọn àgba na pe, Ẹ duro dè wa nihinyi, titi awa o fi tun pada tọ̀ nyin wá: si kiyesi i, Aaroni ati Huri mbẹ pẹlu nyin: bi ẹnikan ba li ọ̀ran kan, ki o tọ̀ wọn wá.
15Mose si gòke lọ sori òke na, awọsanma si bò òke na mọlẹ.
16Ogo OLUWA si sọkalẹ sori òke Sinai, awọsanma na si bò o mọlẹ ni ijọ́ mẹfa: ni ijọ́ keje o ké si Mose lati ãrin awọsanma wá.
17Iwò ogo OLUWA dabi iná ajonirun li ori òke na li oju awọn ọmọ Israeli.
18Mose si lọ sãrin awọsanma na, o sì gùn ori òke na: Mose si wà lori òke li ogoji ọsán ati ogoji oru.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Eks 24: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa