Eks 23
23
1IWỌ kò gbọdọ gbà ìhin eke: máṣe li ọwọ́ si i pẹlu enia buburu lati ṣe ẹlẹri aiṣododo.
2Iwọ kò gbọdọ tọ̀ ọ̀pọlọpọ enia lẹhin lati ṣe ibi, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sọ̀rọ̀ li ọ̀ran ki o tẹ̀ si ọ̀pọ enia lati yi ẹjọ́ po.
3Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbè talaka li ẹjọ́ rẹ̀.
4Bi iwọ ba bá akọmalu tabi kẹtẹkẹtẹ ọtá rẹ ti o ṣina, ki iwọ ki o mú u pada fun u wá nitõtọ.
5Bi iwọ ba ri kẹtẹkẹtẹ ẹniti o korira rẹ, ti o dubulẹ labẹ ẹrù rẹ̀, ti iwọ iba yẹra lati bá a tú u, iwọ o bá a tú u nitõtọ.
6Iwọ kò gbọdọ yi ẹjọ́ talaka rẹ po li ọ̀ran rẹ̀.
7Takéte li ọ̀ran eke; ati alaiṣẹ ati olododo ni iwọ kò gbọdọ pa: nitoriti emi ki yio dá enia buburu lare.
8Iwọ kò gbọdọ gbà ọrẹ: nitori ọrẹ ni ifọ́ awọn ti o riran loju, a si yi ọ̀ran awọn olododo po.
9Ati pẹlu iwọ kò gbọdọ pọ́n alejò kan loju: ẹnyin sa ti mọ̀ inu alejò, nitoriti ẹnyin ti jẹ́ alejò ni ilẹ Egipti.
10Ọdún mẹfa ni iwọ o si gbìn ilẹ rẹ, on ni iwọ o si kó eso rẹ̀ jọ.
11Ṣugbọn li ọdún keje iwọ o jẹ ki o simi, ki o si gbé jẹ; ki awọn talaka enia rẹ ki o ma jẹ ninu rẹ̀: eyiti nwọn si fisilẹ ni ki ẹran igbẹ ki o ma jẹ. Irú bẹ̃ gẹgẹ ni iwọ o ṣe si agbalá-àjara, ati agbalá-olifi rẹ.
12Ijọ́ mẹfa ni iwọ o ṣe iṣẹ rẹ, ni ijọ́ keje ki iwọ ki o si simi: ki akọmalu rẹ, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ ki o le simi, ki a le tù ọmọ iranṣẹbinrin rẹ, ati alejò, lara.
13Ati li ohun gbogbo ti mo wi fun nyin, ẹ ma ṣọra: ki ẹ má si ṣe iranti orukọ oriṣakoriṣa ki a má ṣe gbọ́ ọ li ẹnu nyin.
14Ni ìgba mẹta ni iwọ o ṣe ajọ fun mi li ọdún.
15Iwọ o kiyesi ajọ aiwukàra: ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu, bi mo ti pa a laṣẹ fun ọ, li akokò oṣù Abibu (nitori ninu rẹ̀ ni iwọ jade kuro ni Egipti); a kò gbọdọ ri ẹnikan niwaju mi li ọwọ́ ofo:
16Ati ajọ ikore, akọ́so iṣẹ rẹ, ti iwọ gbìn li oko rẹ: ati ajọ ikore oko, li opin ọdún, nigbati iwọ ba ṣe ikore iṣẹ oko rẹ tán.
17Ni ìgba mẹta li ọdún ni gbogbo awọn ọkunrin rẹ yio farahàn niwaju Oluwa JEHOFA.
18Iwọ kò gbọdọ ta ọrẹ ẹ̀jẹ ẹbọ mi ti on ti àkara wiwu; bẹ̃li ọrá ẹbọ ajọ mi kò gbọdọ kù titi di ojumọ́.
19Akọ́ka eso ilẹ rẹ ni ki iwọ ki o múwa si ile OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀.
20Kiyesi i, emi rán angeli kan siwaju rẹ lati pa ọ mọ́ li ọ̀na, ati lati mú ọ dé ibi ti mo ti pèse silẹ.
21Kiyesi ara lọdọ rẹ̀, ki o si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, máṣe bi i ninu; nitoriti ki yio dari irekọja nyin jì nyin, nitoriti orukọ mi mbẹ lara rẹ̀.
22Ṣugbọn bi iwọ o ba gbà ohùn rẹ̀ gbọ́ nitõtọ, ti iwọ si ṣe gbogbo eyiti mo wi; njẹ emi o jasi ọtá awọn ẹniti nṣe ọtá nyin, emi o si foró awọn ti nforó nyin.
23Nitoriti angeli mi yio ṣaju rẹ, yio si mú ọ dé ọdọ awọn enia Amori, ati awọn Hitti, ati awọn Perissi, ati awọn ara Kenaani, awọn Hifi, ati awọn Jebusi: emi a si ke wọn kuro.
24Iwọ kò gbọdọ tẹriba fun oriṣa wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn, ki o má si ṣe gẹgẹ bi iṣe wọn: bikoṣepe ki iwọ ki o fọ́ wọn tútu, ki iwọ ki o si wó ere wọn palẹ.
25Ẹnyin o si ma sìn OLUWA Ọlọrun nyin, on o si busi onjẹ rẹ, ati omi rẹ; emi o si mú àrun kuro lãrin rẹ.
26Obinrin kan ki yio ṣẹ́nu, bẹ̃ni ki yio yàgan ni ilẹ rẹ: iye ọjọ́ rẹ li emi ó fi kún.
27Emi o rán ẹ̀ru mi siwaju rẹ, emi o si dà gbogbo awọn enia rú ọdọ ẹniti iwọ o dé, emi o si mu gbogbo awọn ọtá rẹ yi ẹ̀hin wọn dà si ọ.
28Emi o si rán agbọ́n siwaju rẹ, ti yio lé awọn enia Hifi, ati awọn ara Kenaani, ati awọn enia Hitti kuro niwaju rẹ.
29Emi ki yio lé wọn jade kuro niwaju rẹ li ọdún kan; ki ilẹ na ki o má ba di ijù, ki ẹranko igbẹ́ ki o má ba rẹ̀ si ọ.
30Diẹdiẹ li emi o ma lé wọn jade kuro niwaju rẹ, titi iwọ o fi di pupọ̀, ti iwọ o si tẹ̀ ilẹ na dó.
31Emi o si fi opinlẹ rẹ lelẹ, lati Okun Pupa wá titi yio fi dé okun awọn ara Filistia, ati lati aṣalẹ̀ nì wá dé odò nì; nitoriti emi o fi awọn olugbe ilẹ na lé nyin lọwọ; iwọ o si lé wọn jade kuro niwaju rẹ.
32Iwọ kò gbọdọ bá wọn ṣe adehùn, ati awọn oriṣa wọn pẹlu.
33Nwọn kò gbọdọ joko ni ilẹ rẹ, ki nwọn ki o má ba mu ọ ṣẹ̀ si mi: nitori bi iwọ ba sìn oriṣa wọn, yio ṣe idẹkùn fun ọ nitõtọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Eks 23: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.