O si ṣe li ọjọ́ wọnni, ti Mose dàgba, o jade tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ lọ, o si wò iṣẹ wọn: o si ri ara Egipti kan o nlù Heberu kan, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ̀.
O si wò ihin, o wò ọhún, nigbati o si ri pe, kò si ẹnikan, o lù ara Egipti na pa, o si bò o ninu yanrin.
Nigbati o si jade lọ ni ijọ́ keji, kiyesi i, ọkunrin meji ara Heberu mbá ara wọn jà: o si wi fun ẹniti o firan si ẹnikeji rẹ̀ pe, Ẽṣe ti iwọ fi nlù ẹgbẹ rẹ?
On si wipe, Tali o fi ọ jẹ́ olori ati onidajọ lori wa? iwọ fẹ́ pa mi bi o ti pa ara Egipti? Mose si bẹ̀ru, o si wipe, Lõtọ ọ̀ran yi di mimọ̀.
Nigbati Farao si gbọ́ ọ̀ran yi, o nwá ọ̀na lati pa Mose. Ṣugbọn Mose sá kuro niwaju Farao, o si ngbé ilẹ Midiani: o si joko li ẹba kanga kan.
Njẹ alufa Midiani li ọmọbinrin meje, nwọn si wá, nwọn pọn omi, nwọn si kún ọkọ̀ imumi lati fi omi fun agbo-ẹran baba wọn.
Awọn oluṣọ-agutan si wá, nwọn si lé wọn kuro: nigbana ni Mose dide duro, o ràn wọn lọwọ, o si fi omi fun agbo-ẹran wọn.
Nigbati nwọn si padà dé lati ọdọ Reueli baba wọn, o ni Ẽtiri ti ẹnyin fi tète dé bẹ̃ loni?
Nwọn si wipe, Ara Egipti kan li o gbà wa lọwọ awọn oluṣọ-agutan, o si pọn omi to fun wa pẹlu, o si fi fun agbo-ẹran.
O si wi fun awọn ọmọbinrin rẹ̀ pe Nibo li o gbé wà? ẽṣe ti ẹnyin fi ọkunrin na silẹ? ẹ pè e ki o le wá ijẹun.
O si dùn mọ́ Mose lati ma bá ọkunrin na gbé: on si fi Sippora ọmọbinrin rẹ̀ fun Mose.
On si bi ọmọkunrin kan fun u, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Gerṣomu: nitoriti o wipe, Emi ti nṣe atipo ni ilẹ ajeji.