O si ṣe li aṣalẹ ni aparò fò dé, nwọn si bò ibudó mọlẹ; ati li owurọ̀ ìri si sẹ̀ yi gbogbo ibudó na ká. Nigbati ìri ti o sẹ̀ bolẹ si fà soke, si kiyesi i, lori ilẹ ijù na, ohun ribiribi, o kere bi ìri didì li ori ilẹ. Nigbati awọn ọmọ Israeli si ri i, nwọn wi fun ara wọn pe, Kili eyi? nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun na. Mose si wi fun wọn pe, Eyi li onjẹ ti OLUWA fi fun nyin lati jẹ. Eyi li ohun ti OLUWA ti palaṣẹ, ki olukuluku ki o ma kó bi ìwọn ijẹ rẹ̀; òṣuwọn omeri kan fun ẹni kọkan, gẹgẹ bi iye awọn enia nyin, ki olukuluku nyin mú fun awọn ti o wà ninu agọ́ rẹ̀. Awọn ọmọ Israeli si ṣe bẹ̃, nwọn si kó, ẹlomiran pupọ̀jù, ẹlomiran li aito. Nigbati nwọn si fi òṣuwọn omeri wọ̀n ọ, ẹniti o kó pupọ̀ kò ni nkan lé, ẹniti o si kó kere jù, kò ṣe alaito nwọn si kó olukuluku bi ijẹ tirẹ̀. Mose si wi fun wọn pe, Ki ẹnikan ki o má kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀.
Kà Eks 16
Feti si Eks 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Eks 16:13-19
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò