O si ṣe li ọjọ kẹta, ni Esteri wọ̀ aṣọ ayaba rẹ̀, o si duro ni àgbala ile ọba ti o wà ninu, lọgangan ile ọba: ọba si joko lori ìtẹ ijọba rẹ̀ ni ile ọba, ti o kọjusi ẹnu-ọ̀na ile na. O si ṣe nigbati ọba ri ti Esteri ayaba duro ni àgbala, on si ri ore-ọfẹ loju rẹ̀: ọba si nà ọ̀pá alade wura ti o wà lọwọ rẹ̀ si Esteri. Esteri si sunmọ ọ, o si fi ọwọ kàn ori ọpá alade na. Nigbana ni ọba bi i pe, kini iwọ nfẹ́, Esteri ayaba? ati kini ẹ̀bẹ rẹ̀? ani de idajì ijọba li a o si fi fun ọ.
Kà Est 5
Feti si Est 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Est 5:1-3
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò