Est 1:13-22

Est 1:13-22 YBCV

Ọba si bi awọn ọlọgbọ́n, ti nwọn moye akokò, (nitori bẹ̃ni ìwa ọba ri si gbogbo awọn ti o mọ̀ ofin ati idajọ: Awọn ti o sunmọ ọ ni Karṣina, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena, ati Memukani, awọn ijoye Persia ati Media mejeje, ti nri oju ọba, ti nwọn si joko ni ipò ikini ni ijọba). Pe, gẹgẹ bi ofin, Kini ki a ṣe si Faṣti ayaba, nitoriti on kò ṣe bi Ahaswerusi ọba ti paṣẹ fun u, lati ọwọ awọn ìwẹfa rẹ̀ wá? Memukani si dahùn niwaju ọba ati awọn ijoye pe, Faṣti ayaba kò ṣẹ̀ si ọba nikan, ṣugbọn si gbogbo awọn ijoye, ati si gbogbo awọn enia ti o wà ni ìgberiko Ahaswerusi ọba. Nitori ìwa ayaba yi yio tàn de ọdọ gbogbo awọn obinrin, tobẹ̃ ti ọkọ wọn yio di gigàn loju wọn, nigbati a o sọ ọ wi pe, Ahaswerusi ọba paṣẹ pe, ki a mu Faṣti ayaba wá siwaju rẹ̀, ṣugbọn on kò wá. Awọn ọlọla-obinrin Persia ati Media yio si ma wi bakanna li oni yi fun gbogbo awọn ijoye ọba ti nwọn gbọ́ ìwa ti ayaba hù. Bayi ni ẹ̀gan pipọ̀-pipọ̀, ati ibinu yio dide. Bi o ba dara loju ọba, ki aṣẹ ọba ki o ti ọdọ rẹ̀ lọ, ki a si kọ ọ pẹlu awọn ofin Persia ati Media, ki a má ṣe le pa a dà, pe, ki Faṣti ki o máṣe wá siwaju Ahaswerusi ọba mọ, ki ọba ki o si fi oyè ayaba rẹ̀ fun ẹgbẹ rẹ̀ ti o san jù u lọ. Ati nigbati a ba si kede aṣẹ ọba ti on o pa yi gbogbo ijọba rẹ̀ ka, (nitori on sa pọ̀) nigbana ni gbogbo awọn obinrin yio ma bọ̀wọ fun ọkọ wọn, ati àgba ati ewe. Ọ̀rọ na si dara loju ọba ati awọn ijoye; ọba si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Memukani: Nitori on ran ìwe si gbogbo ìgberiko ọba, si olukulùku ìgberiko gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati si olukulùku enia gẹgẹ bi ède rẹ̀, ki olukulùku ọkunrin ki o le ṣe olori ni ile tirẹ̀, ati ki a le kede rẹ̀ gẹgẹ bi ède enia rẹ̀.