Est 1:13-22

Est 1:13-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọba si bi awọn ọlọgbọ́n, ti nwọn moye akokò, (nitori bẹ̃ni ìwa ọba ri si gbogbo awọn ti o mọ̀ ofin ati idajọ: Awọn ti o sunmọ ọ ni Karṣina, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena, ati Memukani, awọn ijoye Persia ati Media mejeje, ti nri oju ọba, ti nwọn si joko ni ipò ikini ni ijọba). Pe, gẹgẹ bi ofin, Kini ki a ṣe si Faṣti ayaba, nitoriti on kò ṣe bi Ahaswerusi ọba ti paṣẹ fun u, lati ọwọ awọn ìwẹfa rẹ̀ wá? Memukani si dahùn niwaju ọba ati awọn ijoye pe, Faṣti ayaba kò ṣẹ̀ si ọba nikan, ṣugbọn si gbogbo awọn ijoye, ati si gbogbo awọn enia ti o wà ni ìgberiko Ahaswerusi ọba. Nitori ìwa ayaba yi yio tàn de ọdọ gbogbo awọn obinrin, tobẹ̃ ti ọkọ wọn yio di gigàn loju wọn, nigbati a o sọ ọ wi pe, Ahaswerusi ọba paṣẹ pe, ki a mu Faṣti ayaba wá siwaju rẹ̀, ṣugbọn on kò wá. Awọn ọlọla-obinrin Persia ati Media yio si ma wi bakanna li oni yi fun gbogbo awọn ijoye ọba ti nwọn gbọ́ ìwa ti ayaba hù. Bayi ni ẹ̀gan pipọ̀-pipọ̀, ati ibinu yio dide. Bi o ba dara loju ọba, ki aṣẹ ọba ki o ti ọdọ rẹ̀ lọ, ki a si kọ ọ pẹlu awọn ofin Persia ati Media, ki a má ṣe le pa a dà, pe, ki Faṣti ki o máṣe wá siwaju Ahaswerusi ọba mọ, ki ọba ki o si fi oyè ayaba rẹ̀ fun ẹgbẹ rẹ̀ ti o san jù u lọ. Ati nigbati a ba si kede aṣẹ ọba ti on o pa yi gbogbo ijọba rẹ̀ ka, (nitori on sa pọ̀) nigbana ni gbogbo awọn obinrin yio ma bọ̀wọ fun ọkọ wọn, ati àgba ati ewe. Ọ̀rọ na si dara loju ọba ati awọn ijoye; ọba si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Memukani: Nitori on ran ìwe si gbogbo ìgberiko ọba, si olukulùku ìgberiko gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati si olukulùku enia gẹgẹ bi ède rẹ̀, ki olukulùku ọkunrin ki o le ṣe olori ni ile tirẹ̀, ati ki a le kede rẹ̀ gẹgẹ bi ède enia rẹ̀.

Est 1:13-22 Yoruba Bible (YCE)

Ọba bá fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n ní òye nípa àkókò, (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ọba máa ń ṣe sí gbogbo àwọn tí wọ́n mọ òfin ati ìdájọ́. Àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọn ni: Kaṣena, Ṣetari, ati Adimata, Taṣiṣi ati Meresi, Masena ati Memkani, àwọn ìjòyè meje ní Pasia ati Media. Àwọn ni wọ́n súnmọ́ ọn jù, tí ipò wọn sì ga jùlọ). Ọba bi wọ́n pé, “Gẹ́gẹ́ bí òfin, kí ni kí á ṣe sí Ayaba Faṣiti, nítorí ohun tí ọba pa láṣẹ, tí ó rán àwọn ìwẹ̀fà sí i pé kí ó ṣe kò ṣe é.” Memkani bá dáhùn níwájú ọba ati àwọn ìjòyè pé, “Kì í ṣe ọba nìkan ni Faṣiti kò kà sí, bíkòṣe gbogbo àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè ìjọba Ahasu-erusi ọba. Nǹkan tí Faṣiti ṣe yìí yóo di mímọ̀ fún àwọn obinrin, àwọn náà yóo sì máa fi ojú tẹmbẹlu àwọn ọkọ wọn. Wọn yóo máa wí pé, ‘Ọba ṣá ti ranṣẹ sí ayaba pé kí ó wá siwaju òun rí, tí ó kọ̀, tí kò lọ.’ Láti òní lọ, àwọn obinrin, pàápàá àwọn obinrin Pasia ati ti Media, tí wọ́n ti gbọ́ ohun tí Ayaba ṣe yóo máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ sí àwọn ìjòyè. Èyí yóo sì mú kí aifinipeni ati ibinu pọ̀ sí i. Nítorí náà bí ó bá wu ọba, kí ọba pàṣẹ, kí á sì kọ ọ́ sinu ìwé òfin Pasia ati ti Media, tí ẹnikẹ́ni kò lè yipada, pé Faṣiti kò gbọdọ̀ dé iwájú ọba mọ́, kí ọba sì fi ipò rẹ̀ fún ẹlòmíràn tí ó sàn jù ú lọ. Nígbà tí a bá kéde òfin yìí jákèjádò agbègbè rẹ, àwọn obinrin yóo máa bu ọlá fún àwọn ọkọ wọn; ọkọ wọn kì báà jẹ́ talaka tabi olówó.” Inú ọba ati àwọn ìjòyè dùn sí ìmọ̀ràn yìí, nítorí náà ọba ṣe bí Memkani ti sọ. Ó fi ìwé ranṣẹ sí gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀, ati sí gbogbo agbègbè ati àwọn ẹ̀yà, ní èdè kaluku wọn, pé kí olukuluku ọkunrin máa jẹ́ olórí ninu ilé rẹ̀.

Est 1:13-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ní ìgbà gbogbo, ọba máa ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ní ìmọ̀ òfin àti ìdájọ́, ó sọ ọ́ fún àwọn amòye tí wọ́n mòye àkókò, àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọba àwọn wọ̀nyí ni Karṣina, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena àti Memukani, àwọn ọlọ́lá méje ti Persia àti Media tí wọ́n ṣe pàtàkì sí ọba, wọ́n sì tún wà ní ibi gíga ní ìjọba. Ó béèrè pé, “Kí ni a lè ṣe sí ayaba Faṣti gẹ́gẹ́ bí òfin? Nítorí kò tẹríba fún àṣẹ ọba Ahaswerusi tí àwọn ìwẹ̀fà ọba sọ fún un.” Memukani sì dáhùn níwájú ọba àti àwọn ọlọ́lá pé, “Ayaba Faṣti ti ṣe búburú, kì í ṣe sí ọba nìkan ṣùgbọ́n sí gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ ọba Ahaswerusi. Nítorí ìwà ayaba yìí yóò tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn obìnrin, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ wọn yóò di gígàn lójú u wọn, wọn yóò sì sọ pé, ọba Ahaswerusi pàṣẹ pé kí á mú ayaba Faṣti wá síwájú òun, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti wá. Ní ọjọ́ yìí gan an ni àwọn ọlọ́lá obìnrin Persia àti ti Media tí wọ́n ti gbọ́ nípa ìwà ayaba wọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀ sí gbogbo àwọn ìjòyè ọba bákan náà. Àfojúdi àti àìnírẹ́pọ̀ tí kò lópin yóò wà. “Nítorí náà, bí ó bá tọ́ lójú ọba, jẹ́ kí ó gbé àṣẹ ọba jáde, kí ó sì jẹ́ kí ó wà ní àkọsílẹ̀ pẹ̀lú òfin Persia àti Media, èyí tí kò le é parẹ́, pé kí Faṣti kí ó má ṣe wá síwájú ọba Ahaswerusi. Kí ọba sì fi oyè ayaba rẹ̀ fún ẹlòmíràn tí ó sàn jù ú lọ. Nígbà náà tí a bá kéde òfin tí ọba ṣe ká gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin ni yóò bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó kéré títí dé ọ̀dọ̀ ẹni ńlá.” Ìmọ̀ràn yìí sì tẹ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ́rùn, nítorí náà ọba ṣe gẹ́gẹ́ bí Memukani ṣé sọ. Ó kọ̀wé ránṣẹ́ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ọba rẹ̀, ó kọ̀wé sí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn, Ó tẹnumọ́ ní èdè oníkálùkù pé kí olúkúlùkù ọkùnrin máa ṣàkóso ilé rẹ̀.