ẸNYIN ọmọ, ẹ mã gbọ ti awọn õbi nyin ninu Oluwa: nitoripe eyi li o tọ́. Bọ̀wọ fun baba ati iya rẹ (eyi ti iṣe ofin ikini pẹlu ileri), Ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wà pẹ li aiye. Ati ẹnyin baba, ẹ máṣe mu awọn ọmọ nyin binu: ṣugbọn ẹ mã tọ́ wọn ninu ẹkọ́ ati ikilọ Oluwa. Ẹnyin ọmọ-ọdọ, ẹ mã gbọ ti awọn oluwa nyin nipa ti ara, pẹlu ibẹru ati iwarìri, ni otitọ ọkàn nyin, bi ẹnipe si Kristi; Ki iṣe ti arojuṣe bi awọn ti nwù enia; ṣugbọn gẹgẹ bi awọn ẹrú Kristi, ẹ mã ṣe ifẹ Ọlọrun lati inu wá; Ẹ mã fi inu rere sin bi si Oluwa, kì si iṣe si enia: Bi ẹnyin ti mọ pe ohun rere kohunrere ti olukuluku ba ṣe, on na ni yio si gbà pada lọdọ Oluwa, ibã ṣe ẹrú, tabi omnira. Ati ẹnyin oluwa, ẹ mã ṣe ohun kanna si wọn, ẹ mã din ibẹru nyin kù; bi ẹnyin ti mọ pe Oluwa ẹnyin tikaranyin si mbẹ li ọrun; kò si si ojuṣãju enia lọdọ rẹ̀. Lakotan, ará mi, ẹ jẹ alagbara ninu Oluwa, ati ninu agbara ipá rẹ̀.
Kà Efe 6
Feti si Efe 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Efe 6:1-10
3 Awọn ọjọ
Ìfọkànsìn yìí jẹ́ ìtẹ̀síwájú nínú ọ̀wọ́ apá mẹ́ta kan lórí ìbátan Kristian. Apa akoko wo ajosepo laarin iyawo ati oko re, apakan yii yoo da lori ajosepo laarin awọn obi ati awọn ọmọ. Bí a ṣe ń lọ́wọ́ sí apá yìí nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, ìfẹ́ ọkàn mi ni pé kí a fún àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn òbí wa àti àwọn ọmọ wa lókun sí ògo Ọlọ́run.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò