ẸNYIN li a si ti sọ di àye, nigbati ẹnyin ti kú nitori irekọja ati ẹ̀ṣẹ nyin,
Ninu eyiti ẹnyin ti nrin rí gẹgẹ bi ipa ti aiye yi, gẹgẹ bi alaṣẹ agbara oju ọrun, ẹmí ti nṣiṣẹ nisisiyi ninu awọn ọmọ alaigbọran:
Ninu awọn ẹniti gbogbo wa pẹlu ti wà rí ninu ifẹkufẹ ara wa, a nmu ifẹ ara ati ti inu ṣẹ; ati nipa ẹda awa si ti jẹ ọmọ ibinu, gẹgẹ bi awọn iyoku pẹlu.
Ṣugbọn Ọlọrun, ẹniti iṣe ọlọrọ̀ li ãnu, nitori ifẹ nla rẹ̀ ti o fi fẹ wa,
Nigbati awa tilẹ ti kú nitori irekọja wa, o sọ wa di ãye pẹlu Kristi (ore-ọfẹ li a ti fi gba nyin là).
O si ti ji wa dide pẹlu rẹ̀, o si ti mu wa wa joko pẹlu rẹ̀ ninu awọn ọrun ninu Kristi Jesu:
Pe ni gbogbo ìgba ti mbọ ki o ba le fi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀ ti o pọ rekọja han ninu iṣeun rẹ̀ si wa ninu Kristi Jesu.
Nitori ore-ọfẹ li a ti fi gbà nyin là nipa igbagbọ́; ati eyini kì iṣe ti ẹnyin tikaranyin: ẹ̀bun Ọlọrun ni:
Kì iṣe nipa iṣẹ, ki ẹnikẹni má bã ṣogo.
Nitori awa ni iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ ti a ti dá ninu Kristi Jesu fun iṣẹ rere, ti Ọlọrun ti pèse tẹlẹ, ki awa ki o le mã rìn ninu wọn.
Nitorina ẹ ranti pe, nigba atijọ ri, ẹnyin ti ẹ ti jẹ Keferi nipa ti ara, ti awọn ti a npè ni Akọla ti a fi ọwọ ṣe li ara npè li Alaikọla,
Pe li akokò na ẹnyin wà laini Kristi, ẹ jẹ ajeji si anfani awọn ọlọtọ Israeli, ati alejo si awọn majẹmu ileri nì, laini ireti, ati laini Ọlọrun li aiye:
Ṣugbọn nisisiyi ninu Kristi Jesu ẹnyin ti o ti jìna réré nigba atijọ rí li a mu sunmọ tosi, nipa ẹ̀jẹ Kristi.
Nitori on ni alafia wa, ẹniti o ti ṣe mejeji li ọ̀kan, ti o si ti wó ogiri ìkélé nì ti mbẹ lãrin;
O si ti fi opin si ọta nì ninu ara rẹ̀, ani si ofin aṣẹ wọnni ti mbẹ ninu ilana; ki o le fi awọn mejeji dá ẹni titun kan ninu ara rẹ̀, ki o si ṣe ilaja,
Ati ki o le mu awọn mejeji ba Ọlọrun làja ninu ara kan nipa agbelebu; o si ti pa iṣọta na kú nipa rẹ̀:
O si ti wá, o si ti wasu alafia fun ẹnyin ti o jìna réré, ati fun awọn ti o sunmọ tosi:
Nitori nipa rẹ̀ li awa mejeji ti ni ọ̀na nipa Ẹmí kan sọdọ Baba.
Njẹ nitorina ẹnyin kì iṣe alejò ati atipo mọ́, ṣugbọn àjumọ jẹ ọlọ̀tọ pẹlu awọn enia mimọ́, ati awọn ará ile Ọlọrun;
A si ngbé nyin ró lori ipilẹ awọn aposteli, ati awọn woli, Jesu Kristi tikararẹ̀ jẹ pàtaki okuta igun ile;
Ninu ẹniti gbogbo ile na, ti a nkọ ṣọkan pọ, ndagbà soke ni tẹmpili mimọ́ ninu Oluwa:
Ninu ẹniti a ngbé nyin ró pọ pẹlu fun ibujoko Ọlọrun ninu Ẹmí.