O si ṣe, nigbati ẹnyin gbọ́ ohùn nì lati ãrin òkunkun na wá, ti òke na si njó, ti ẹnyin sunmọ ọdọ mi, gbogbo olori awọn ẹ̀ya nyin, ati awọn àgba nyin:
Ẹnyin si wipe, Kiyesi i, OLUWA Ọlọrun wa fi ogo rẹ̀ ati titobi rẹ̀ hàn wa, awa si ti gbọ́ ohùn rẹ̀ lati ãrin iná wá: awa ti ri li oni pe, OLUWA a ma ba enia sọ̀rọ̀, on a si wà lãye.
Njẹ nisisiyi ẽṣe ti awa o fi kú? nitoripe iná nla yi yio jó wa run: bi awa ba tun gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa, njẹ awa o kú.
Nitoripe tani mbẹ ninu gbogbo araiye ti o ti igbọ́ ohùn Ọlọrun alãye ti nsọ̀rọ lati ãrin iná wá, bi awa ti gbọ́, ti o si wà lãye?
Iwọ sunmọtosi, ki o si gbọ́ gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun wa yio wi: ki iwọ ki o sọ fun wa gbogbo ohun ti OLUWA Ọlọrun wa yio sọ fun ọ: awa o si gbọ́, awa o si ṣe e.
OLUWA si gbọ́ ohùn ọ̀rọ nyin, nigbati ẹnyin sọ fun mi; OLUWA si sọ fun mi pe, emi ti gbọ́ ohùn ọ̀rọ awọn enia yi, ti nwọn sọ fun ọ: nwọn wi rere ni gbogbo eyiti nwọn sọ.
Irú ọkàn bayi iba ma wà ninu wọn, ki nwọn ki o le ma bẹ̀ru mi, ki nwọn ki o si le ma pa gbogbo ofin mi mọ́ nigbagbogbo, ki o le dara fun wọn, ati fun awọn ọmọ wọn titilai!
Lọ wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ sinu agọ́ nyin.
Ṣugbọn, iwọ, duro nihin lọdọ mi, emi o si sọ ofin nì gbogbo fun ọ, ati ìlana, ati idajọ, ti iwọ o ma kọ́ wọn, ki nwọn ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ na ti mo ti fi fun wọn lati ní.
Nitorina ki ẹnyin ki o ma kiyesi ati ṣe bi OLUWA Ọlọrun nyin ti paṣẹ fun nyin: ki ẹnyin ki o máṣe yi si ọtún tabi si òsi.
Ki ẹnyin ki o si ma rìn ninu gbogbo ọ̀na ti OLUWA Ọlọrun nyin palaṣẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le yè, ki o si le dara fun nyin, ati ki ẹnyin ki o le mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ ti ẹnyin yio ní.