Ṣugbọn ẹnyin ti o faramọ́ OLUWA Ọlọrun nyin, gbogbo nyin mbẹ lãye li oni. Wò o, emi ti kọ́ nyin ni ìlana ati idajọ, bi OLUWA Ọlọrun mi ti paṣẹ fun mi, pe ki ẹnyin ki o le ma ṣe bẹ̃ ni ilẹ na nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a. Nitorina ẹ pa wọn mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn; nitoripe eyi li ọgbọ́n nyin ati oye nyin li oju awọn orilẹ-ède, ti yio gbọ́ gbogbo ìlana wọnyi, ti yio si wipe, Ọlọgbọ́n ati amoye enia nitõtọ ni orilẹ-ède nla yi. Nitori orilẹ-ède nla wo li o wà, ti o ní Ọlọrun sunmọ wọn to, bi OLUWA Ọlọrun wa ti ri ninu ohun gbogbo ti awa kepè e si? Ati orilẹ-ède nla wo li o si wà, ti o ní ìlana ati idajọ ti iṣe ododo to bi gbogbo ofin yi, ti mo fi siwaju nyin li oni? Kìki ki iwọ ki o ma kiyesara rẹ, ki o si ṣọ́ ọkàn rẹ gidigidi, ki iwọ ki o má ba gbagbé ohun ti oju rẹ ti ri, ati ki nwọn ki o má ba lọ kuro li àiya rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; ṣugbọn ki iwọ ki o ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ
Kà Deu 4
Feti si Deu 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Deu 4:4-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò