Deu 30:11-20

Deu 30:11-20 YBCV

Nitori aṣẹ yi ti mo pa fun ọ li oni, kò ṣoro jù fun ọ, bẹ̃ni kò jìna rere si ọ. Kò sí li ọrun, ti iwọ iba fi wipe, Tani yio gòke lọ si ọrun fun wa, ti yio si mú u wá fun wa, ki awa ki o le gbọ́ ọ, ki a si le ṣe e? Bẹ̃ni kò sí ni ìha keji okun, ti iwọ iba fi wipe, Tani yio rekọja okun lọ fun wa, ti yio si mú u fun wa wá, ki awa ki o le gbọ́ ọ, ki a si le ṣe e? Ṣugbọn ọ̀rọ na li o wà nitosi rẹ girigiri yi, li ẹnu rẹ, ati li àiya rẹ, ki iwọ ki o le ma ṣe e. Wò o, emi fi ìye ati ire, ati ikú ati ibi, siwaju rẹ li oni; Li eyiti mo palaṣẹ fun ọ li oni lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀, ati lati ma pa aṣẹ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ati idajọ rẹ̀ mọ́, ki iwọ ki o le yè, ki o si ma bisi i, ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le busi i fun ọ ni ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a. Ṣugbọn bi àiya rẹ ba pada, ti iwọ kò ba si gbọ́, ṣugbọn ti iwọ di ẹni fifà lọ, ti iwọ si mbọ oriṣa, ti iwọ si nsìn wọn; Emi sọ fun nyin li oni, pe ṣiṣegbé li ẹnyin o ṣegbé; ẹnyin ki yio mu ọjọ́ nyin pẹ lori ilẹ, nibiti iwọ ngòke Jordani lọ lati gbà a. Emi pè ọrun ati ilẹ jẹri tì nyin li oni pe, emi fi ìye ati ikú, ibukún ati egún siwaju rẹ: nitorina yàn ìye, ki iwọ ki o le yè, iwọ ati irú-ọmọ rẹ: Ki iwọ ki o le ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati ki iwọ ki o le ma gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, ati ki iwọ ki o le ma faramọ́ ọ: nitoripe on ni ìye rẹ, ati gigùn ọjọ́ rẹ: ki iwọ ki o le ma gbé inu ilẹ na ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, ati fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fi fun wọn.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa