Deu 30:11-20

Deu 30:11-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nitori aṣẹ yi ti mo pa fun ọ li oni, kò ṣoro jù fun ọ, bẹ̃ni kò jìna rere si ọ. Kò sí li ọrun, ti iwọ iba fi wipe, Tani yio gòke lọ si ọrun fun wa, ti yio si mú u wá fun wa, ki awa ki o le gbọ́ ọ, ki a si le ṣe e? Bẹ̃ni kò sí ni ìha keji okun, ti iwọ iba fi wipe, Tani yio rekọja okun lọ fun wa, ti yio si mú u fun wa wá, ki awa ki o le gbọ́ ọ, ki a si le ṣe e? Ṣugbọn ọ̀rọ na li o wà nitosi rẹ girigiri yi, li ẹnu rẹ, ati li àiya rẹ, ki iwọ ki o le ma ṣe e. Wò o, emi fi ìye ati ire, ati ikú ati ibi, siwaju rẹ li oni; Li eyiti mo palaṣẹ fun ọ li oni lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀, ati lati ma pa aṣẹ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ati idajọ rẹ̀ mọ́, ki iwọ ki o le yè, ki o si ma bisi i, ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le busi i fun ọ ni ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a. Ṣugbọn bi àiya rẹ ba pada, ti iwọ kò ba si gbọ́, ṣugbọn ti iwọ di ẹni fifà lọ, ti iwọ si mbọ oriṣa, ti iwọ si nsìn wọn; Emi sọ fun nyin li oni, pe ṣiṣegbé li ẹnyin o ṣegbé; ẹnyin ki yio mu ọjọ́ nyin pẹ lori ilẹ, nibiti iwọ ngòke Jordani lọ lati gbà a. Emi pè ọrun ati ilẹ jẹri tì nyin li oni pe, emi fi ìye ati ikú, ibukún ati egún siwaju rẹ: nitorina yàn ìye, ki iwọ ki o le yè, iwọ ati irú-ọmọ rẹ: Ki iwọ ki o le ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati ki iwọ ki o le ma gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, ati ki iwọ ki o le ma faramọ́ ọ: nitoripe on ni ìye rẹ, ati gigùn ọjọ́ rẹ: ki iwọ ki o le ma gbé inu ilẹ na ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, ati fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fi fun wọn.

Deu 30:11-20 Yoruba Bible (YCE)

“Nítorí pé òfin tí mo fun yín lónìí kò le jù fun yín, kì í sìí ṣe ohun tí apá yín kò ká. Kì í ṣe òkè ọ̀run ni ó wà, tí ẹ óo fi wí pé, ‘Ta ni yóo gun òkè ọ̀run lọ, tí yóo lọ bá wa mú un sọ̀kalẹ̀ wá, kí á lè gbọ́ kí á sì pa á mọ́?’ Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní òdìkejì òkun tí ẹ óo fi wí pé, ‘Ta ni yóo la òkun kọjá fún wa, tí yóo lọ bá wa mú un wá kí á lè gbọ́ kí á sì pa á mọ́?’ Ṣugbọn nítòsí yín ni ọ̀rọ̀ náà wà, ó wà lẹ́nu yín, ó sì wà ninu ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé ẹ lè ṣe é. “Wò ó, mo gbé ikú ati ìyè kalẹ̀ níwájú yín lónìí, bákan náà ni mo sì gbé ire ati ibi kalẹ̀. Tí ẹ bá pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́ bí mo ti fun yín lónìí, tí ẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, tí ẹ̀ ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin, ìlànà ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì máa pọ̀ sí i. OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà tí yóo sì di tiyín. Ṣugbọn bí ọkàn yín bá yipada, tí ẹ kọ̀, tí ẹ kò gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ kí wọn fà yín lọ bọ àwọn oriṣa, tí ẹ sì ń sìn wọ́n, mo wí fun yín gbangba lónìí pé, ẹ óo parun. Ẹ kò ní pẹ́ rárá lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gòkè Jọdani lọ gbà, tí yóo sì di tiyín. Mo fi ilẹ̀ ati ọ̀run ṣe ẹlẹ́rìí níwájú yín lónìí, pé mo fun yín ní anfaani láti yan ikú tabi ìyè, ati láti yan ibukun tabi ègún. Nítorí náà, ẹ yan ìyè kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lè wà láàyè. Ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀, kí ẹ sì máa súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè pẹ́ láyé, kí ẹ sì lè máa gbé orí ilẹ̀ tí OLUWA búra láti fún àwọn baba yín, àní Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu.”

Deu 30:11-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí àṣẹ yìí tí mo pa fún ọ lónìí, kò ṣòro jù fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni kò kọjá agbára rẹ. Kò sí ní ọ̀run, tí ìwọ kò bá fi wí pé, “Ta ni yóò gòkè lọ sí ọ̀run fún wa, tí yóò sì mú wa fún wa, kí àwa lè gbọ́, kí a sì le ṣe é?” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ìhà kejì Òkun, tí ìwọ ìbá fi wí pé, “Ta ni yóò rékọjá Òkun lọ fún wa, tí yóò sì mú un wá fún wa, kí àwa lè gbọ́ ọ, kí a si le ṣe é?” Kì í ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ náà súnmọ́ tòsí rẹ, ó wà ní ẹnu rẹ àti ní ọkàn rẹ kí ìwọ lè máa ṣe é. Wò ó mo gbé kalẹ̀ síwájú u yín lónìí, ìyè àti àlàáfíà, ikú àti ìparun. Ní èyí tí mo pàṣẹ fún ọ ní òní láti máa fẹ́ OLúWA Ọlọ́run rẹ, láti máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ àti láti máa pa àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, àti ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè yè, kí ó sì máa bí sí i, kí OLúWA Ọlọ́run lè bù si fún ọ ní ilẹ̀ náà, ní ibi tí ìwọ ń lọ láti gbà á. Ṣùgbọ́n tí ọkàn an yín bá yí padà tí ìwọ kò sì ṣe ìgbọ́ràn, àti bí o bá fà, lọ láti foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn àti sìn wọ́n, èmi ń sọ fún un yín lónìí yìí pé ìwọ yóò parun láìsí àní àní. O kò ní í gbé pẹ́ ní ilẹ̀ tí ìwọ ń kọjá Jordani láti gbà àti láti ní. Èmi pe ọ̀run àti ilẹ̀ láti jẹ́rìí tì yín ní òní pé, èmi fi ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún síwájú rẹ: nítorí náà yan ìyè, kí ìwọ kí ó lè yè, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ, kí ìwọ kí ó le máa fẹ́ OLúWA Ọlọ́run rẹ, fetísílẹ̀ sí ohùn un rẹ̀, kí o sì dúró ṣinṣin nínú rẹ̀. Nítorí OLúWA ni ìyè rẹ, yóò sì fún ọ ní ọdún púpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.