Deu 26
26
Ọrẹ Ìkórè
1YIO si ṣe, nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ti iwọ si gbà a, ti iwọ si joko ninu rẹ̀;
2Ki iwọ ki o mú ninu akọ́so gbogbo eso ilẹ rẹ, ti iwọ o mú ti inu ile rẹ wá, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ; ki iwọ ki o si fi i sinu agbọ̀n, ki iwọ ki o si lọ si ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si.
3Ki iwọ ki o si tọ̀ alufa na lọ ti yio wà li ọjọ́ wọnni, ki o si wi fun u pe, Emi jẹwọ li oni fun OLUWA Ọlọrun rẹ, pe emi wá si ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba wa lati fi fun wa.
4Ki awọn alufa ki o si gbà agbọ̀n na li ọwọ́ rẹ, ki o si gbé e kalẹ niwaju pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ.
5Iwọ o si dahùn iwọ o si wi niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ pe, Ara Siria kan, ti o nṣegbé ni baba mi, on si sọkalẹ lọ si Egipti, o si ṣe atipo nibẹ̀, ti on ti enia diẹ; nibẹ̀ li o si di orilẹ-ède nla, alagbara, ati pupọ̀:
6Awọn ara Egipti si hùwabuburu si wa, nwọn si pọn wa loju, nwọn si dì ẹrù wuwo rù wa:
7Awa si kepè OLUWA, Ọlọrun awọn baba wa, OLUWA si gbọ́ ohùn wa, o si wò ipọnju wa, ati lãlã wa, ati inira wa:
8OLUWA si mú wa lati Egipti jade wá pẹlu ọwọ́ agbara, ati apa ninà, ati pẹlu ẹrù nla, ati pẹlu iṣẹ-àmi, ati pẹlu iṣẹ-iyanu:
9O si mú wa dé ihin yi, o si fi ilẹ yi fun wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.
10Njẹ nisisiyi, kiyesi i, emi mú akọ́so ilẹ na wa, ti iwọ, OLUWA, fi fun mi. Ki iwọ ki o si gbé e kalẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma foribalẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ:
11Ki iwọ ki o si ma yọ̀ ninu ohun rere gbogbo, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ati fun ara ile rẹ, iwọ, ati ọmọ Lefi, ati alejò ti mbẹ lãrin rẹ.
12Nigbati iwọ ba da idamẹwa asunkun rẹ tán li ọdún kẹta, ti iṣe ọdún idamẹwa, ti iwọ si fi fun ọmọ Lefi, alejò, alainibaba, ati opó, ki nwọn ki o ma jẹ li ẹnubode rẹ, ki nwọn si yó;
13Nigbana ni ki iwọ ki o wi niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ pe, Emi ti mú ohun mimọ́ kuro ninu ile mi, mo si ti fi wọn fun ọmọ Lefi, ati fun alejò, ati fun alainibaba, ati fun opó, gẹgẹ bi gbogbo aṣẹ rẹ ti iwọ ti pa fun mi: emi kò re aṣẹ rẹ kọja, bẹ̃li emi kò gbagbé wọn:
14Emi kò jẹ ninu rẹ̀ ninu ọ̀fọ mi, bẹ̃li emi kò mú kuro ninu rẹ̀ fun ohun aimọ́ kan, bẹ̃li emi kò mú ninu rẹ̀ fun okú: ṣugbọn emi ti gbà ohùn OLUWA Ọlọrun mi gbọ́, emi si ti ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ palaṣẹ fun mi.
15Wò ilẹ lati ibujoko mimọ́ rẹ wá, lati ọrun wá, ki o si busi i fun Israeli enia rẹ, ati fun ilẹ na ti iwọ fi fun wa, bi iwọ ti bura fun awọn baba wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.
Àwọn Eniyan OLUWA
16Li oni OLUWA Ọlọrun rẹ paṣẹ fun ọ lati ma ṣe ìlana ati idajọ wọnyi: nitorina ki iwọ ki o ma pa wọn mọ́, ki iwọ ki o si ma fi gbogbo àiya rẹ ati gbogbo ọkàn rẹ ṣe wọn.
17Iwọ jẹwọ OLUWA li oni pe on ni Ọlọrun rẹ, ati pe iwọ o ma rìn li ọ̀na rẹ̀, iwọ o si ma pa ìlana rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, iwọ o si ma fetisi ohùn rẹ̀:
18OLUWA si jẹwọ rẹ li oni pe iwọ o ma jẹ́ enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, bi on ti ṣe ileri fun ọ, ati pe iwọ o ma pa gbogbo aṣẹ rẹ̀ mọ́;
19On o si mu ọ ga jù orilẹ-ède gbogbo lọ ti o dá, ni ìyin, li orukọ, ati ọlá; ki iwọ ki o le ma jẹ́ enia mimọ́ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 26: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.