Deu 24
24
Kíkọ Iyawo sílẹ̀ ati Títún Igbeyawo ṣe
1BI ọkunrin kan ba fẹ́ obinrin kan, ti o si gbé e niyawo, yio si ṣe, bi obinrin na kò ba ri ojurere li oju ọkunrin na, nitoriti o ri ohun alebù kan lara rẹ̀: njẹ ki o kọ iwé ikọsilẹ fun obinrin na, ki o fi i lé e lọwọ, ki o si rán a jade kuro ninu ile rẹ̀.
2Nigbati on ba si jade kuro ninu ile rẹ̀, on le lọ, ki o ma ṣe aya ọkunrin miran.
3Bi ọkọ rẹ̀ ikẹhin ba si korira rẹ̀, ti o si kọ iwé ikọsilẹ fun u, ti o si fi i lé e lọwọ, ti o si rán a jade kuro ninu ile rẹ̀; tabi bi ọkọ ikẹhin ti o fẹ́ ẹ li aya ba kú;
4Ọkọ rẹ̀ iṣaju, ti o rán a jade kuro, ki o máṣe tun ní i li aya lẹhin ìgba ti o ti di ẹni-ibàjẹ́ tán; nitoripe irira ni niwaju OLUWA: iwọ kò si gbọdọ mu ilẹ na ṣẹ̀, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní.
Oríṣìíríṣìí Àwọn Òfin Mìíràn
5Bi ọkunrin kan ba gbé iyawo titun, ki o máṣe lọ si ogun, bẹ̃ni ki a máṣe fun u ni iṣẹkiṣẹ kan ṣe: ki o ri àye ni ile li ọdún kan, ki o le ma mu inu aya rẹ̀ ti o ní dùn.
6Ẹnikan kò gbọdọ gbà iya-ọ̀lọ tabi ọmọ-ọlọ ni ògo: nitoripe ẹmi enia li o gbà li ògo nì.
7Bi a ba mú ọkunrin kan ti njí ẹnikan ninu awọn arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ Israeli, ti o nsìn i bi ẹrú, tabi ti o tà a; njẹ olè na o kú; bẹ̃ni iwọ o mú ìwabuburu kuro lãrin nyin.
8Ma kiyesi àrun-ẹ̀tẹ, ki iwọ ki o ṣọra gidigidi ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn alufa awọn ọmọ Lefi yio ma kọ́ nyin: bi emi ti pa a laṣẹ fun wọn, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ma kiyesi lati ṣe.
9Ranti ohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe si Miriamu li ọ̀na, nigbati ẹnyin ti Egipti jade wá.
10Nigbati iwọ ba wín arakunrin rẹ li ohun kan, ki iwọ ki o máṣe lọ si ile rẹ̀ lati mú ògo rẹ̀ wá.
11Ki iwọ ki o duro lode gbangba, ki ọkunrin na ti iwọ wín ni nkan, ki o mú ògo rẹ̀ jade tọ̀ ọ wá.
12Bi ọkunrin na ba si ṣe talakà, ki iwọ ki o máṣe sùn ti iwọ ti ògo rẹ̀.
13Bi o ti wù ki o ri iwọ kò gbọdọ má mú ògo rẹ̀ pada fun u, nigbati õrùn ba nwọ̀, ki on ki o le ri aṣọ bora sùn, ki o si sure fun ọ: ododo ni yio si jasi fun ọ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ.
14Iwọ kò gbọdọ ni alagbaṣe kan lara ti iṣe talakà ati alaini, ibaṣe ninu awọn arakunrin rẹ, tabi ninu awọn alejò rẹ ti mbẹ ni ilẹ rẹ ninu ibode rẹ:
15Ni ọjọ́ rẹ̀, ni ki iwọ ki o sanwo ọ̀ya rẹ̀ fun u, bẹ̃ni ki o máṣe jẹ ki õrùn ki o wọ̀ bá a; nitoripe talakà li on, o si gbẹkẹ rẹ̀ lé e: ki o má ba kepè OLUWA si ọ, a si di ẹ̀ṣẹ si ọ lọrùn.
16A kò gbọdọ pa awọn baba nitori ẹ̀ṣẹ awọn ọmọ, bẹ̃ni a kò gbọdọ pa awọn ọmọ nitori awọn baba: olukuluku enia li a o pa nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
17Iwọ kò gbọdọ yi idajọ alejò po, tabi ti alainibaba; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe gbà aṣọ opó ni ogò:
18Ṣugbọn ki iwọ ki o ranti pe iwọ ti ṣe ẹrú ni Egipti, OLUWA Ọlọrun rẹ si gbà ọ silẹ kuro nibẹ̀: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ lati ma ṣe nkan yi.
19Nigbati iwọ ba kore rẹ li oko rẹ, ti iwọ ba si gbagbé ití-ọkà kan silẹ ninu oko, ki iwọ ki o máṣe pada lọ mú u: ki o le ma jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó: ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le ma busi i fun ọ, ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo.
20Nigbati iwọ ba ngún igi olifi rẹ, ki iwọ ki o máṣe tun pada wò ẹka rẹ̀: ki eyinì ki o jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó.
21Nigbati iwọ ba nká eso ọgbà-àjara rẹ, ki iwọ ki o máṣe peṣẹ́ lẹhin rẹ: ki eyinì ki o jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó.
22Ki iwọ ki o si ma ranti pe iwọ ti ṣe ẹrú ni ilẹ Egipti: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ lati ma ṣe nkan yi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 24: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.