Ki iwọ ki o dá idamẹwa gbogbo ibisi irugbìn rẹ, ti nti oko rẹ wá li ọdọdún.
Niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti on o gbé yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, ni ki iwọ ki o si ma jẹ idamẹwa ọkà rẹ, ti ọti-waini rẹ, ati ti oróro rẹ, ati akọ́bi ọwọ́-ẹran rẹ, ati ti agbo-ẹran rẹ; ki iwọ ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ nigbagbogbo.
Bi ọ̀na na ba si jìn jù fun ọ, ti iwọ ki yio fi le rù u lọ, tabi bi ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si ba jìn jù fun ọ, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba bukún ọ:
Njẹ ki iwọ ki o yi i si owo, ki iwọ ki o si dì owo na li ọwọ́ rẹ, ki o si lọ si ibi na, ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn.
Ki iwọ ki o si ná owo na si ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́, si akọmalu, tabi agutan, tabi ọti-waini, tabi ọti lile kan, tabi si ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́: ki iwọ ki o si ma jẹ nibẹ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma yọ̀, iwọ, ati awọn ara ile rẹ:
Ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ; iwọ kò gbọdọ kọ̀ ọ silẹ; nitoriti kò ní ipín tabi iní pẹlu rẹ.
Li opin ọdún mẹta ni ki iwọ ki o mú gbogbo idamẹwa ibisi rẹ wa li ọdún na, ki iwọ ki o si gbé e kalẹ ninu ibode rẹ:
Ati ọmọ Lefi, nitoriti kò ní ipín tabi iní pẹlu rẹ, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ ninu ibode rẹ, yio wá, nwọn o si jẹ nwọn o si yó; ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le bukún ọ ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ ti iwọ nṣe.