Nigbana ni ọba paṣẹ, nwọn si mu Danieli wá, nwọn si gbé e sọ sinu iho kiniun. Ọba si dahùn o wi fun Danieli pe, Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ nsìn laisimi, on o gbà ọ la.
A si yi okuta kan wá, nwọn si gbé e ka oju iho na; ọba si fi oruka edidi rẹ̀ sami si i, ati oruka edidi awọn ijoye rẹ̀, ki ohunkohun máṣe yipada nitori Danieli.
Nigbana ni Ọba wọ̀ ãfin rẹ̀ lọ, o si fi oru na gbàwẹ: bẹ̃li a kò si gbé ohun-elo orin kan wá siwaju rẹ̀: orun kò si wá si oju rẹ̀.
Nigbana ni Ọba dide li afẹmọjumọ, o si yara kánkan lọ si ibi iho kiniun na.
Nigbati o si sunmọ iho na o fi ohùnrére ẹkun kigbe si Danieli: ọba dahùn o si wi fun Danieli pe, Danieli! iranṣẹ Ọlọrun alãye! Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ nsìn laisimi, ha le gbà ọ lọwọ awọn kiniun bi?
Nigbana ni Danieli wi fun ọba pe, ki ọba ki o pẹ.
Ọlọrun mi ti ran angeli rẹ̀, o si dì awọn kiniun na lẹnu, ti nwọn kò fi le pa mi lara: gẹgẹ bi a ti ri mi lailẹṣẹ niwaju rẹ̀; ati niwaju rẹ pẹlu, ọba, emi kò si ṣe ohun buburu kan.
Nigbana ni ọba yọ̀ gidigidi, o si paṣẹ pe, ki nwọn ki o fà Danieli jade kuro ninu iho. Bẹ̃li a si fa Danieli jade kuro ninu iho, a kò si ri ipalara lara rẹ̀, nitoriti o gbà Ọlọrun rẹ̀ gbọ́.
Ọba si paṣẹ, pe ki a mu awọn ọkunrin wọnni wá, ti o fi Danieli sùn, nwọn si gbé wọn sọ sinu iho kiniun, awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn aya wọn. Ki nwọn ki o to de isalẹ iho, awọn kiniun bori wọn, nwọn si fọ egungun wọn tũtu.