Dan 3:28-30

Dan 3:28-30 YBCV

Nigbana ni Nebukadnessari dahùn o si wipe, Olubukún li Ọlọrun Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ẹniti o rán angeli rẹ̀ ti o si gbà awọn iranṣẹ rẹ̀ la, ti o gbẹkẹ le e, nwọn si pa ọ̀rọ ọba da, nwọn si fi ara wọn jìn, ki nwọn ki o má ṣe sìn, tabi ki nwọn ki o tẹriba fun oriṣakoriṣa bikoṣe Ọlọrun ti awọn tikarawọn. Nitorina, emi paṣẹ pe, olukulùku enia, orilẹ, ati ède, ti o ba sọ ọ̀rọ odi si Ọlọrun Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, a o ke e wẹwẹ, a o si sọ ile rẹ̀ di àtan: nitori kò si Ọlọrun miran ti o le gbà ni là bi iru eyi. Nigbana ni ọba gbé Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego leke ni igberiko Babeli.