Dan 10:12-13

Dan 10:12-13 YBCV

Nigbana ni o wi fun mi pe, má bẹ̀ru, Danieli: lati ọjọ kini ti iwọ ti fi aiya rẹ si lati moye, ti iwọ si npọ́n ara rẹ loju niwaju Ọlọrun rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ rẹ, emi si wá nitori ọ̀rọ rẹ. Ṣugbọn balogun ijọba Persia nì dè mi li ọ̀na li ọjọ mọkanlelogun: ṣugbọn, wò o, Mikaeli, ọkan ninu awọn olori balogun wá lati ràn mi lọwọ: emi si di ipò mi mu lọdọ awọn ọba Persia.