Kol 4:10-11

Kol 4:10-11 YBCV

Aristarku, ẹlẹgbẹ mi ninu tubu ki nyin, ati Marku, ọmọ arabinrin Barnaba (nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbà aṣẹ: bi o ba si wá sọdọ nyin, ẹ gbà a), Ati Jesu, ẹniti a npè ni Justu, ẹniti iṣe ti awọn onila. Awọn wọnyi nikan ni olubaṣiṣẹ mi fun ijọba Ọlọrun, awọn ẹniti o ti jasi itunu fun mi.